top of page

IRAN KETA

ORO OLORUN YOO JERI TAKO O NIKEHINI

           

              Mo ri Arakunrin kan ti o wo aso funfun bi  ti  Angeli  sugbon  o  sun  si  ibiti  ainiye  ona  ti  pade,  o  si  je  ona ti won da oda  si,  arakunrin  yi  sun  sile  bi  igbati  o ku,  bakanna  o  dabi were, lehinna mo  ri  obinrin  kan  ti  o  nkoja  lo,  bi  o  se  nkoja  lo,  o de ibiti arakunrin yi sun sile  si  bi  igbati  o  ku,  obinrin  na  kunle  o  si  gbadura  pe  oju  to  fi  nso oun ati  awon  omo  oun  ki  o  mase  fi sun, ko ma so oun ati awon omo oun, lehinna o lo, nigbati o npada bo, o tun ya iwaju eniti o sun na, o si tun kunle o dupe pe mo  lo  lay o  mo  bo  layo,  oju ti  o fi nso won ki o mase fi sun. Bi o se fe dide lori ikunle pe ki oun ma lo beeni okunrin ti o wo aso funfun ti o dabi were na di arabinrin  na mu, mo si ri awon eniyan miran wa lati ba obinrin na bebe.

 Okunrin ti o wo aso funfun yi dahun pe ti enikeni ba le fi idi oro yi han nigbana loun yoo to fi arabinrin yi sile. Lehin osu kan ti mo ti ngba adura fun kini idi oro yi. Oluwa to mi wa, o si fi idi oro na han mi.

 

 

 

IRAN KERIN

ORO OLORUN YOO JERI TAKO O NIKEHIN II

 

                   Oluwa  wipe  mo  so  ifarahan  yi  kale,  ko  si  kede  re  pe ojo kan nbo ti oro  Olohun  yoo  jeri  tako  eniyan  pe  sebi  o  gbo  oro  Olorun  ri, kilo de ti o  ko  paa  mo?   kilo  de  ti  o  ko se ife re.

 

(a) Oluwa wipe okunrin were ti o sun si ibiti ainiye ona ti pade ni ORO OLORUN, Oluwa awon  oluwa.

 

(b) Itumo were ti o je ni pe were ni a ka ORO OLOHUN si ti ko si ni itumo si wa, awon ibiti o ye fun anfani tiwa la ndimu ti a si nka.

 

(d) Aso funfun ti o wo ni pe sibe bi Oro Olohun se dabi were loju wa sibe mimo ni ORO OLOHUN.

 

(e) Oluwa wipe o sun si ibiti ainiye ona ti pade tumo si pe ainiye ni Oro ti Oun Oluwa ti ran si Orile ede alaye lati satunse aye atipe lati igbati aye ti wa, ainiye ona ni ORO na ti gba wa si aye lati wa satunse aye.

 

(e) Pe o sun tabi o ku ni pe igbagbo opolopo eniyan ni pe Oro Olorun ti ku tabi sun pe ki nsise bi ti atijo.

 

(f) Awa eniyan ti Olorun da ni obinrin to wa ngbadura nigbagbogbo niwaju oro Olohun ti nse Bibeli ati Alkurani eyiti nse Jesu, sugbon to je pe igbagbo wa romo ise iyanu nikan ti a nri gba lodo Olohun sugbon ki nse lati se ife RE.

 

(g) Pe obinrin yi nlo gbadura niwaju re nigbagbogbo ni pe ohun ti a ntori re nsin Olohun ni ise ami ati ise iyanu ki nse lati se ife Olohun.

 

(gb) Oluwa  wipe  o  ji  dide   lati  di  arabinrin  yi  mu  ni  pe  ojo   nbo  ti  oro Olohun  yoo  di  o  mu  lati  bere  ohun  ti  o  gbele  aye  se  atipe  se  Oun  o  wa lati  yi  o  pada,  sebi  ohun  ti  o  fe  ju  nilati  ma  gba  adura  laise  ife  Re,  ojo kan si nbo ti yoo je Eleri tako eniyan. Qur 4:159.

 

(I) Awon to wa nbebe yi ni awon to nbebe fun oku lehin ti o ku, ni igbagbo pe adura won le pa ise buburu won re.

 

(h) Pe ko fi arabinrin yi sile, Oluwa wipe lehin iku ti ORO OLORUN si ti di o mu lati bere ohun ti o gbele aye se, ko si atunse mo.

 

Ronupiwada loni nitori Olorun ko fe iku elese bikose pe ko ronupiwada, Oluwa wipe ohun ti a ntori re nlo si odo Oluwa ni ise ami ati ise iyanu ti a o ri gba lodo re, paapa nitori abo lori wa. Opolopo lo nlo ile Olohun yaala Soosi tabi Mosalasi ti olukuluku si npolongo ohun ti o nbe lodo re sugbon ki nse lati se ife re tabi pa ofin re mo nitori sibe ni iwa buburu eniyan nposi. Nigbati a ba de ile Olorun, a o ma jo a o si ma yo sugbon nigbati a ba de ibi oro Olorun ko je nkankan loju wa, awon ibiti a si mo ju ninu oro Olohun yala Bibeli tabi Alkurani ni awon ibiti a o fi segun ota tabi bere fun ibukun sugbon ti a ba de ibiti o nsoro nipa iwa buburu wa, igbagbo wa ni pe o ti sun tabi a le fi oore ofe gbe. Nigbamiran a o tun fi oro Olorun se irori lati sun nitori iberu ota ati awon emi esu,  se ife Olorun,  ki o si je mimo ni ona re gbogbo, ki oro Olohun ma ba je eleri tako o wipe fun gbogbo odun ti o fi gbe Bibeli tabi Alkurani nje o se ife re, yipada loni ki o to peju fun o.

 

IRAN KARUN

 

            Oluwa  si  fi  arakunrin  kan  han  mi  ti  o jade  lati  inu  oko  (car)  olowo iyebiye  kan,  bi  o  se  jade  lati  inu  oko  (car)  na  ti o fese te ile (ground) lati ma  wo  ile  ise  re  lo,  beni  ile  (ground)  mu  duro  ti  ko  le  lo  mo,  bi  mo se nwoye pe ki lohun to nsele beni  ile  (ground)  soro.  O  si  wi  fun mi pe okunrin olowo ti mo ri yi, oun ile (ground) ko ni pe gba eto oun lowo re,  mo dahun pe iru eto wo lo ni lowo arakunrin olowo na, ile (ground) dami lohun pe Olorun lo ni emi re sugbon oun ile lo ni iyoku to nbe lara re.

Bi Olorun ba si ti gba eto tire, oun ile (ground) na yoo si gba eto toun  atipe ti Olorun ba ti gba emi re, Oun ile (ground) loun ni iyoku. O ni sugbon eda eniyan ko bikita nipa eyi, o ni lori ile yi ni awon eniyan yoo duro le ti won a si ma se ise ibi pelu ise buburu gbogbo, won a si ma gbe ori ile se ibaje. Lehinti eniyan ba ku awon oku ti nsokun oku yoo si duro lori oun ile lati ma se opolopo inawo ifekufe, aye ijekuje ati lati so wipe won nse isinku fun eto ti oun ti gba, ti won o si mo ibiti eto Olorun to gba eyiti nse emi nlo boya alujona tabi orun apadi.

 

 

OKU NSOKUN OKU LAYE

 

                  Eyin eniyan nikehin ojo yi, e tile ti gbagbe wipe bi ojo Nuha ni yoo ri ti awon eniyan nje aye ifekufe, e nsinku bi igbati e o mo pe oku nsokun oku laye ni. Nje o mo pe awon ohun kan wa ti o romo oku? Ikini ni pe e padanu enikan ti e feran ti ko seese boya e le ri mo laelae, ikeji ni pe ibo ni oku na nlo se ijoba orun tabi orun apadi? iketa ni pe awon iwa ti mo mo pelu enito ku, ibugbe wo lo to si ninu mejeji. Ikerin, nigbati mi o mo ibiti o nlo, nje o seese ka tun pade nitori oku nsokun oku laye ni tabi eko wo ni mo ri ko nipa igbe aye eni to ku?.

E jeki a ranti itan ti Jesu so fun wa nipa igbe aye Lasaru ati oloro, bi o tile jepe igbe aye ti awon mejeji gbe laye ni Bibeli salaye pelu ere igbe aye won lehinti won fi aye sile, sugbon nipa bi won se se isinku won ni a ko mo sibe ti a ba wo iru ipo ti oloro yi wa, iru aso ti o nwo pelu awon ounje adidun ti o nje lojojumo, eyi fihan iru posi ti won o lo lati fi sin oloro yi, iru aso ti won o wo fun oku re, opo elere ti yoo wa sere nibi isinku re pelu opo ifekufe aye miran, o tun seese ki won ko orin “ile lo lo tarara baba rele o ile lo lo tarara”. Bi o tile jepe inu irora ati inira lo wa sibe ile lo lo lotito. Bakanna  e  jeki  a  wo  isinku  Lasaru  pe eniti  ko  ri ounje oojo je ti o si ku sinu osi, nitori inu aisan ti o wa, o seese ki ebi re ti ma toro iku fun, o tun seese ki o jepe won o gbe ile won o ju sinu re, ko si orin ile lo lo tarara nitori won o le gbagbo pe yoo lo sibi isimi, ko si posi to dara, ko si elere ti yoo wa sere nibe, sibe arakunrin yi lo sinu itura.

 

Tani eni to nbikita lati keko lara oku toku, tani eni ti o ronu jinle nipa eniti o ku pe nibo lo nlo, igbe aye wo lo ngbe ko to di pe olojo de, beni oku nsokun oku laye ni. Dipo ki a wo awokose igbe aye awon omo isreali ni ojo wonni ti won nfi ogoji ojo sokun eniti won padanu ti o seese ki won ri mo, sugbon nikehin ojo yi nse ni e nfile poti ti e nfona roka, ti e o ma daso tuntun, ebi oku a tun ma tara oku sowo, e gbagbe pe oku nsokun oku laye ni.

 

Ohun ti o se ni lanu ni pe nigbati eniyan ba ku, e o sokunsokun, won o ma parowa si yin, lehin wakati die si e o ma ronu owo aseye nla to to si eto ile to gba, awon miran a tun je gbese kale, iru aso wo ni yoo lo? Lehinti e ba de iboji lati feruferu e o tun sokun die, lehinti e ba kuro nibi iboji e o wa bere ijo ati ariya repete laisi ironu ojo wo ni yoo kan mi beni oku nsokun oku laye ni. Dipo ki e yipada ninu iwa buburu, igbagbo yin ni pe o ti ba tire lo niyen, ma gbagbe tire nbo lorun oku nwi, ronupiwada loni ki iwo na le wo ibi isimi, maje ki ijoba Olohun ka ifekufe isinku sise mo o lowo bi ti ojo Nuha, ko si ranti pe oku nsokun oku laye. Eyiti o tumo si pe, gbogbo eniyan ni yoo ku sugbon awon ti o wa laaye nsokun lori oku laironu nipa ise owo won tabi pe dajudaju awon na yoo ku ni ojo kan. 

 

 

NAIJIRIA ILU SODOMU ATI EGIPTI TI EMI

 

                  Gbo iwo orile ede Naijiria larin awon ile keferi ti nse ile Afrika, Olohun gbe o dide lati mu asotele na se ninu re, iwo ti o dabi Sodomu ati Egipti lotito, ni Naijiria ti okunrin ti nba okunrin se ti obinrin nba obinrin lopo, ni ile ti e ti gbe orisa ga ju Olorun lo, ni ile ti e ti ni igbagbo ninu awon ti nfi alupayida se iyanu, ni ile ti e ti nfi eniyan se irubo nitori ipo, ni ile ti akonisise ati aninilara ti nje alaini niya, ni ile ti amunisin ti nmu alaini sin, ni ile ti ojise olohun eke ti po ju  ojise  Olohun  otito  lo,  ranti  loni  ohun  ti  o  gbehin  Sodomu  ati  Egipti ti isaju ki o ronupiwada iwo Naijiria. Eyin o mo pe Orile Ede ti Agbere, Pansaga ati Ipaniyan ba je ise owo won ki ntete ri ojurere Olorun. Nigbawo ni ojise eke ko ni kun inu re iwo Naijiria, Orile Ede ti o nbo orisa nfa ibinu Olorun ni paapa ti Olorun ni ise pataki lati se ninu re. Eyin na e wo ainiye eto atunse ati ona abayo ti e ti la kale sibe ko si ona abayo, e lo teriba fun Olorun ki e si bebe fun idariji ese, iwo Orile Ede ti o ti  kun fun ayo nigbakan ri nigbati Ile Ijosin yaala Mosalasi tabi Soosi kun inu re lo wa fun inira, lo pada to Olorun lo.

 

Iwo ti o fe dari ijoba Naijiria lo so ara re di Ojise Olorun lati kapa ese, ipaniyan  ati iwa ibaje kuro ni Orile Ede yi, o si ri pe yoo seese. Iwo Naijiria ti oro Olorun sotele nipa re pe Olorun yoo lo lati da isokan ati Alafia pada fun eniyan (Isa. 19:-25, Saka. 3:1-10, Al Maidah 54, Al Yunusa 47-49. Jona ti isaju kigbe ironupiwada si Ninefe, won si yipada. Naijiria mase duro de akoko ti Olorun yoo funrare la inu re koja ti yoo si mu ohun gbogbo to lodi si tire kuro yala Eniyan, Emi tabi Ijoba. Yipada loni ki Olorun le mu owo re ni rere wa fun o, titi di akoko ti Oluwa yoo si pepe ikehin fun isoji ikehin ojo yi, ki alaafia ki o ma bisi fun gbogbo eniyan bi a se nka Awari Keji ti nse AMI JONA.

bottom of page