top of page

AWARI

 

Ope ni fun Olorun fun aanu re lori gbogbo wa, oore ofe Olorun ni, eyi ni Joshua  onihinrere ikehin ojo ti a gbe dide lati wasun ironupiwada fun gbogbo eniyan ki o to di pe opin de. (Seka 3:1-10) Olohun fi aanu     re wo ile yi lati gbe okan ninu awon eleri  meji na dide lati wasun isokan, ironupiwada ati alaafia  fun awon eniyan.  Ihinrere na ti Bibeli ati Alkurani sotele nipa re wipe ki yoo saaju akoko re jade ti  akoko re ba  to ki yoo lora ni wakati kan ti yoo fi jade (Isa 19:19-25, Al Yunusa  47-49) ki alaafia ma bisi fun gbogbo eniyan bi a se nka AWARI akoko yi.                                      

                                                        

IRAN KINNI

Lehinti mo gbadura tan beeni awon Angeli meji sokale wa bami, won si gbe mi lo  si ori oke kan, mo si ba opo Angeli nibe, okan ninu Angeli ti o mu mi rin irinajo na wi fun mi pe ki nsowopo pelu won lati gbadura ni oruko Jesu ki Oluwa tun aye se. Bi a se ngbadura yi beeni awon miran ninu Angeli nfi ede kewu gba ti won bi  igbati won nperun, mo si da won duro pe kilode ti won o pe oruko Jesu, okan ninu won da mi lohun pe oro kansoso na ni a jumo nso pe oruko Jesu ti mo fi ngba adura ni awon na fi ngba adura, ki Oluwa tun aye se ti mo so ni awon na fi ngba adura won ni ki nlo ma gba adura ki Oluwa tun aye se.                                                                                                                                          

 

Oluwa gbe mi lo si inu ile nla kan ti o kun fun ohun elo agbara, lojiji ni ina njo ninu  ile na, bi mo se ngbiyanju lati sa jade beeni Emi Oluwa dari mi kuro ninu yara agbara na lo si inu aginju, bi mo se wo inu aginju na beeni arakunrin kan njade kuro ninu aginju na. Nigbati mo wo inu aginju na ti o je igbo kijikiji, agbami, okunkun biribiri si bo inu aginju na, awon emi airi si kun inu re ti won nda  eniyan loro ti won si npon eniyan loju. Beeni emi Oluwa fi mi sile fun igba die, gbogbo eniyan lo si nkigbe fun irora pupo. Bi mo se wo inu aginju yi ni mo ti  nkigbe pe Jeki imole ki o wa sugbon sibe okunkun biribiri ni, mo si gbo ohun kan ti o wipe ile aye ni iwo sese wo yi.

Lehinna emi Oluwa tun bale mi, o si gbemi wo inu orun lo, nigbati o  gbemi de ibikan ninu orun, o dami duro, ibe je kiki imole. Lehinna mo ri Bibeli ni owo mi otun, Alkurani ni owo osi, ohun kan si jade lati inu orun wa pe oro ti un o ma gbo yi ati ase yi njade lati ori ite OGA OGO, mi o gbudo yipada tabi ko sile nitori o je majemu oun Olorun fun gbogbo agbaye nikehin ojo yi, beeni ibeere jade lati  ori ite na wa pe:

Ibeere:Ki lohun to wa ni owo otun?

 

Idahun:Bibeli

Ibeere:Ki lohun to wa ni owo osi mi ?

Idahun:Alkurani

Ibeere:Ki lohun ti mejeji je?

Idahun:Oro Olorun         

 Ibeere:Tani Jesu nse ?

Idahun:Omo Olohun

Ibeere:Tani Jesu nse pelu oro mejeji ti mo ko dani

Idahun:Mi o mo

Beni oro na tesiwaju pe Bibeli to nbe lowo mi otun ni Jesu, Kurani to nbe lowo  mi osi ni Jesu ati pe Jesu yi gan ni OGA OGO fi ropo ara re si aye. Mo dahun pe bawo la se nkede eleyi ni orile aye ti awon eniyan fi ngbagbo, O dahun pe ayafi ti nba le pa majemu orun ati osupa re lohun ti mo so nikehin yi ko fi ni wa si imuse.

            Oluwa wipe ese awon baba nla wa lo fa wipe awon baba nla wa lo gbimo po lati mo odi kan ori eyiti yoo kan orun ki won le ma goke re orun ki won si tun sokale wa si aye eyiti Oluwa wipe won wadi Oun Olohun, won tun ni ki awon ko ilu kan ki won ma ba tuka. O tumo si pe won lodi si ase Oun Olorun nigbati oun Oluwa wipe ki won ma bisi, ki won ma gbayin lori ile, ki won si se ikawo aye. Oluwa wipe mo da eniyan lede ru, mo si gegun si aye pe won o ni gbede ara won mo Gen 11:1-8, eyiti o tumo si pe imo won o ni se okan mo nitori eda eniyan je eda ti nwadi Olorun. lati akoko na ohun kansoso ni Oun Oluwa nran  wa si aye sugbon ona ti Oun yoo gba ran wa ni yoo fa iyapa ati idarudapo.

Nitorinaa emi ki nse Olorun Kristeni tabi ti Musulumi, Oun ti mo se si aye ni ko ye awon eniyan, ohun ti emi Oluwa ko da ni awon eniyan da funra won sugbon mo ti seleri pe nikehin ojo emi Oluwa o kede ohun ijinle Mi. (Ifi 10:1-7) lati ran isokan ati alaafia wa nitorinaa iwo gbe Bibeli ati Alkurani pelu opo eniyan lati lo kede isokan ati ironupiwada si aye nitori esin ni awon eniyan mi nsin nigbati iwa ati ise won  buru ju ti akoko Nuha lo.  

 

O  ni ase yi njade lati ori ite OGAOGO mi o gbudo yipada tabi ko sile nitori oro mejeji yi  pelu Eri yi ni e o fi josin si oun Olorun nikehin ojo yi, lati inu orun  na ni mo ti kigbe pe Jeki imole ko wa nigbati emi Oluwa yoo fi da mi pada, ibi gbogbo ti je imole.

 

IRAN KEJI

EROGBA OLORUN LORI DIDA ENIYAN

           

              Oluwa wipe lehinti mo fi ina da awon Angeli, ohun ti won ma nse niwaju mi ni lati ma gbe Oun Olorun ga. Oluwa wipe mo  ipinnu miran pe ti mo ba fi amo da awon eda miran lati ma gbe mi ga beeni Olohun da ibugbe na ti a npe ni ile aye pelu ohun gbogbo ti eniyan nilo ni ori ile aye lati le jeki eniyan mo pe a ti da ohun ti yoo je ti yoo mu ki a to da oun nikehin beeni Olorun ni fi Oun  iyato si aarin Angeli ati eniyan.

Awon Angeli le ri Olorun lojukoju sugbon eda eniyan ko ni oore ofe lati ri Olohun, Ina ni mo fi da awon Angeli sugbon amo ni mo fi da eniyan, awon Angeli ni oore ofe lati sokale wa si aye ki won si tun goke lo si orun sugbon eda eniyan ko le kuro ni aye ayafi ti o ba ku. Ti Angeli ba dese ko si aye ironupiwada sugbon eda eniyan ni oore ofe lati sokun fun ironupiwada. Sugbon ise kan to pa Angeli ati eniyan po ni lati ma yin Olorun nigba gbogbo eyiti opo eniyan fi sile laise nitori won tobi ju eniti o seda won lo, oba ti titobi re ko lafiwe.

 

IRAN KETA

ESE KINNI LEHIN DIDA ENIYAN

Gen 3:1-24, Surah Arafi 19-25

            Lehinti Olohun pari dida aye ti o si da Adamu ati Efa sinu ogba edeni lati ma gbe nibiti o je mimo ti Olorun yasoto lati ma be eniyan wo. O si tun je ibi mimo ti aimo o gbudo wo eyiti a le pe ni Tempili Olohun ni aye. Lehinna Olorun fun won ni ofin kan wipe e mase ba tempili na je, won ru ofin na nitori itanje esu. Ese kinni yi ko fi aye ironupiwada sile ko to di pe Olorun gbe idajo re kale beni Olohun ko gbe ojise Kankan dide lati wasun ironupiwada ko to di pe Olorun mu idajo wa nitori ese na je ese aimo Olorun to. Idajo ese kinni yi le eniyan jade lati ibi itura lo sinu iponju ninu eyi ni eniyan wa titi ti won fi da ese keji.

 

IRAN KERIN

ESE KEJI LEHIN DIDA ENIYAN

Gen 6:4-22, Surah Arafi 59-64

           

             Awon eniyan ti nbisi won  nposi lori ile aye ki won to da ese yi, ko i ti si ofin  tabi  ilana  lati  ma  josin  si  Olohun  sugbon  awon  eniyan  ti  mo buburu yato  si  rere,  ese  yi  je  iwa  ati  ise  eniyan  to  buru  niwaju  Olorun   pelu  ero ibi  ni  okan  eniyan. “Aye  si  baje  niwaju  Olohun,  aye  si  kun fun iwa agbara, Olorun  si  bojuwo  aye,  si  kiyesi  o  baje:  nitori  olukuluku  eniyan  ti  ba  iwa re  je  li  aye .......... Nitori  aye  kun  fun  iwa  agbara  lati  owo  won ”.  Ese  yi  fi aye ironupiwada sile eyiti Oluwa fi gbe Nuha (Noa) dide lati wasun ironupiwada  kuro  ninu  ese  fun  gbogbo  eniyan.  Lehinti  ojo  idajo  pe Olohun  gba  okan  Nuha  ati  ebi  re  la,  o  si  mu  iparun  wa  si ori awon elese.

Ijiya ese keji yi poju ese kinni lo nitori ese akoko je ese si Olohun funrare tabi aimo Olorun to nigbati ese keji je iwa ati ise eniyan ti o buru. Lehinna Olorun tun ba eniyan da majemu lati mase fi ikun omi pa aye run mo, sibe awon ebi Noa (Nuha) ti Olohun gbala ntesiwaju lati ma gbe ninu iponju ese akoko.

 

IRAN KARUN

ESE KETA LEHIN DIDA ENIYAN

Gen 11:1-11

           

             Awon eniyan ti nbisi lehin ikun omi Nuha (Noa) ki won to da ese yi, gbogbo eniyan lo da ese na bi o tile jepe ko i ti si ofin tabi ilana ti eniyan le ma fi gbe igbe aye re, sibe awon eniyan ti mo buburu yato si rere. Awon baba nla wa gbimo po lati mo odi kan lati goke re orun ki won si tun sokale wa si aye atipe won tun gbimo po lati ko ilu kan ki won ma ba tuka kiri eyiti o tumo si pe won wadi  Olorun nigbati ikeji je pe won lodi si ase Olohun nitori Oluwa wipe e ma bisi ki e si se ikawo aye.

Oluwa wipe ese yi je ese aimo oun Olorun to ati idi pataki ti mo fi da eniyan ati iyato to wa larin Angeli ati eniyan ni pe a ko fun eniyan ni oore ofe lati ri Olohun lojukoju. Ese keta yi ko fi aye ironupiwada sile ko to di pe Olorun mu idajo re wa, idajo ese keta yi fi iponju kun iponju eniyan laye nitori eniyan ti ngbe ninu iponju ese kinni nigbati Olorun le eniyan jade nibi itura lo sinu iponju ki Olohun to wa fi iponju kun iponju eniyan nipase ese keta.

Read more
bottom of page