IRAN KEFA
OLORUN FI IPONJU KUN IPONJU ENIYAN
Olorun da eniyan lede ru, Olohun tun gegun si aye pe awon eniyan o ni gbede ara won mo, abe idarudapo yi ni ilu tabi orile ede wa, lati ori omo ile iwe alakobere ni elomiran yoo ti fe lu omo pa nitori ko tete gbo ede oyinbo, ede ti Oluwa daru mu olukuluku ka eniti ko gbo ede re si ajeji tabi ota, ilu, orile ede npa ara won nitori ile, aala ile, ipo. Idarudapo ede so isokan nu lorile ede aye, ara Isreali ko le ba ara Palestini gbe ni alaafia beeni Olorun kanna lo seda ohun gbogbo. Olohun wipe mo gegun si aye pe awon eniyan o ni gbo ede ara won, o wipe itumo re ni pe isokan ko ni si larin awon eniyan mo, ki won ma ba ni isimi lati wadi oun Olorun. Egun yi so isokan nu larin awon eniyan, isokan sonu larin idile, ilu, eya tabi orile ede, larin ile ijosin yala soosi tabi mosalasi. Enito nka Bibeli ko le josin pelu enito nka Alkurani be si ni ohun kansoso ni Olohun loun ran wa, ona ti Oun Oluwa yoo gba ran wa ni yoo fa iyapa ati idarudapo nitori ese keta. Egun yi gbe esin dide ni eyiti Oluwa wipe mi o da, sibe ni Olorun ni mo se ileri pe ni ikehin “enikini yoo tun pada pe enikeji ti a da lede ru won o tun jo jumo josin ni isokan (Isa 19:19-25, Seka 3:10, Suratul Yunusa 19-20, 47-49).
IRAN KEJE
OHUN MERIN TI EGUN NA MU WA
Oluwa wipe igbo ati aginju ti a dari mi lo ni ile aye ninu emi, ohun merin ti mo ri ni ohun merin ti o nbe ni abe egun aigbede ara wa ninu emi lati fi pon eniyan loju ki eniyan ma le ni isimi lati wadi OunOlohun. Ikini ni okunkun biribiri to bo aye ki awon eniyan ma le ri ohun ti Oun Oluwa se si aye, ikeji ni agbami ti Oluwa wipe ile tabi iyangbe ile duro lori agbami ti awon oke si yi ka, eniti o ba jin sinu agbami, akoko na ni iru eni be nwa ninu wahala tabi isoro. Iketa ni igbo kijikiji eyiti o tumo si ogun, enikini si enikeji, ebi si ara won, ilu si ara won, orile ede si orile ede. Ikerin ni awon emi okunkun ti o npon ni loju ni aye, idi niyi ti awon emi okunkun fi nso pe owo won ni Olohun ko aye le lowo.
Nitorinaa bi eniyan ba gbadura ti o bo ninu okunkun lo sinu imole ki o to fehinti lati ma wadi Olohun ogun ti dide si, ki o to tun gbadura, ki o to ni isegun, ki o to fehinti lati ma wadi eniti o da orun ati aye, o ti jin sinu agbami, ki o to gbadura bo ninu re lati ma wadi Olohun awon emi okunkun tun ti koju si, ki o to bo kuro lowo won lati ma simi, o tun ti bere lati ibere. Eyi ni iponju ti inu emi ti o nbe ni idi egun na ki awon eniyan ma le ni isimi lati ma wadi Olorun.
IRAN KEJO
ISE IRANSE SAAJU AKOKO ISREALI
Lehinti Oluwa tu awon eniyan ka nibiti olukuluku tedo si won a ma rubo si Olohun, won a si ma lo ohun ti won ri lati fi rubo si Olohun, sibe Oluwa wipe nko binu rara nitori ko I ti si ofin tabi ilana ti eniyan le ma Lo lati fi josin si Olorun. Olohun wipe oun Oluwa a ma wa ran awon ojise kankan si ilu, eya tabi orile ede lati ma yo awon eniyan tabi alaimokan kuro ninu ide, iponju tabi ogun paapa kuro ninu iponju egun ese keta ni ona ti o je mimo. Olorun a si ma wo awon ojise yi ni ewu agbara lati lo, fun apeere ni ile Yoruba sango, orunmila ati beebe lo, kaakiri gbogbo agbaye ni Olorun ni Oun ti ma ngbe won dide.
IRAN KESAN
ISUBU ISE IRANSE NAA
Lehinti awon eniyan wonyi baku awon eniyan paapa awon olutele won yoo so won di olorun ajeji tabi orisa ti won nforibale fun, won si nse etutu tabi rubo si won, won a tun ma di imule pelu awon emi okunkun to nbe ni oju orun ati orile aye. Awon emi inu omi paapa awon emi ti Olohun ran lati pon eniyan loju pelu awon Angeli buburu gbogbo ti Olorun le jade ni orun wa si aye.
Olohun wipe mo pinnu mo si pa ilana na re eyi si ni isubu ilana na, enikeni ti o ba si wa ninu ilana na ti o si nbo orisa tabi foribale fun olohun ajeji wa ninu ewu idajo nitori Oluwa wipe mo ran ododo wa si aye iru eni be kuna lati gba ododo gbo, eyi ni ipinlese bi awon eniyan se bere si nforibale tabi bo orisa ni ori ile aye, won a si ma se odun fun un. Gbogbo agbaye lo si nbo orisa yi ko to di pe Olorun bere atunse aye nipa gbigbe Abrahamu dide nipase eniti Mose dide fun ise iranse akoko lehin tituka ti Olohun tu awon eniyan ka.
Fun apeere Olorun wipe “ese awon ara Amori ko i ti kun to (Gen 15:16) Olorun wipe mo duro fun irinwo odun o le ko to di pe mo pa awon eniyan ile na run ti mo si jogun ile na fun awon omo isreali ti Olorun ran fun ihinrere akoko.
IRAN KEWA
IHINRERE LATI AKOKO ABRAHAMU
Olorun wipe mo gbe Abrahamu dide lati se ni iyasoto lagbaye ati lati ran iran awon omo re fun atunse aye eyiti Olohun ti ipase re gbe Isreali dide. Oluwa wipe mo gbe Isreali dide lati je awokose fun gbogbo agbaye ki awon orile ede agbaye le ri bi won se nsin Mi ati bi mo se wa pelu won, ki awon orile ede toku le ti ipase won yipada si Olohun sugbon Isreali ganna lo tun wa sin orisa ju orile ede to ku lo eyiti o fa isubu won. Isreali paapa ko mo idi ti a fi gbe won dide ni Oluwa wi. Lehinna ni OGA OGO ni mo ni ipinnu miran lati fi ara han ni ona miran lati mu ORO re jade lati fihan pe Olohun ti gbogbo agbaye yoo ri lojukoju niyi, eyiti Jesu fi powe wipe emi omo Olohun, eyiti OGA OGo wipe ki nse omo bikose oba awon oba, Oluwa awon oluwa, Olorun gbogbo agbaye nitori eniyan lo bere fun ati ri Olohun lojukoju. Oun si ni oba
ti kokoro ati wo orun nbe ni owo re. “Atipe ko ni si enikan ninu awon Oni-tira ayafi ki o gba a gbo siwaju ki o to ku. ti o ba si di ojo ajinde yoo je eleri tako won (AL Nisai 159, Joh 14:6). O ni emi ona, otito ati iye eniyan gbagbe pe oro Olorun ni ona otito ati iye fun enikeni ti o gba ni oba ti ko tele ni oro asan ni, Lehin ti Olohun gbe ododo ikehin ojo yi dide fun enikeni ti o tele ni oro ti ko gba ni oba tabi Olohun re asan ni, Oluwa wipe Oun na ni BiBeli, Oun na ni Alkurani, Oun na ni Olorun gbogbo agbaye, O wipe ohun ti mo se si aye ni ko ye awon eniyan.
Oro ti Mose ati awon Woli gbo nigbati Olorun gbe Isreali dide lati je awokose fun gbogbo agbaye ti a pe ni majemu laelae. Oro kansoso na ti OGA OGO pe ni Jesu Oluwa nigbati awon eniyan fe ri Olohun won lojukoju nigbati Isreali ti a gbe dide lati je awokose fun gbogbo agbaye bo orisa ju orile ede to ku lo. Oro kansoso na ti OGA OGO ti bo inu eje lati fi setutu ese araye. Oro kansoso na ti Muhammadu gbo ti o nje Alkurani lehin igoke re orun Jesu ti ihinrere si ngbile, Oluwa wipe mo bojuwo aye mo si ri pe ti imo awon eniyan ba se okan sibe ni won yoo tesiwaju lati ma wadi Olohun atipe sibe ni olorun ajeji sinsin ngbile si ni aye atipe opin ko i ti de.
Olohun wipe mo ranti majemu mi fun Ismaeli, mo si gbe iran omo re ti nse Muhammadu dide lati pa idameta eniyan ti o nsin orisa run nipase ogun eyiti Oun paapa fi idi re mule pe “A pa ogun jija ni ase fun yin, sugbon o je ohun ti e korira, o le je pe eyin korira nkankan ti nkan na yoo je ore fun yin; besini eyin yoo feran nkankan ti yoo je aburu fun yin. Olorun mo eyin ko mo” (Surah Bakorah 216) Ihinrere ti Angeli kefa fun ipe fun lati pa idameta eniyan run (Ifihan 9:13-21). Oro kansoso na ti Muhammadu ri ifarahan si ti Oluwa pe ni arole sugbon ti Olohun ko so itumo tani arole na nse (Surah Bakorah 30) eyiti Alkurani salaye pe “ O seese k i Olorun ti da awon kan saaju Adamu ati awon omo re ” eyiti Alkurani tun fidi re mule pe awon onigbagbo ododo ni awon ti o ni igbagbo si ihinrere Musa ( Mose ) .Iwe Genesis fidi re mule pe Adamu ati Efa ni Olorun koko da. Olohunwipe pepe ati ilana ni ohun to yato nigbati Olorun si pepe kinni ni orun won lo apoti eri, nigbati Olorun si pepe keji ni orun won lo adura gbigba ni oruko Oluwa ati ilana re, nigbati Olorun si pepe keta won lo ikirun ati ilana re lati fi josin lori pepe na bi a se nreti akoko awon keferi fun gbogbo agbaye nikehin yi. (Isaiah 19:19-25, Sekariah 3:1-10, Ifihan 11:1-2, Surah Yunusa 47-49).