ESE KERIN LEHIN DIDA ENIYAN PELU IGBE FUN IRONUPIWADA
​
Egun aisi isokan yi lo wa titi Olohun fi won Tempili re to si bojuwo aye to si ri pe ese ti awon eniyan nda lakoko yi buru ju ti akoko Nuha lo. Oluwa wipe lehinti Muhammadu pari ihinrere eyiti nse pepe keta ti Olorun si ni orun. Olorun wipe o ti wa ninu asotele pe “Awon eniyan ti o ku ti won ko pa nipase ogun tabi ise iranse Annabi Muhammadu ku, ni won ko ni yipada kuro ninu iwa buburu won. “Sugbon awon eniyan iyoku ti a ko ti ipa iyonu wonyi pa, ko ni si ironupiwada ise owo won, ki won mase sin awon emi esu ati ere wura ati ti fadaka ati ti ide ati ti okuta ati ti igi mo, awon ti ko le riran tabi ki won gboran tabi ki won rin. Beni won ko ronupiwada eniyan pipa won tabi oso won tabi agbere won tabi ole won (Ifihan 9:20-21, Qur 2:216)
Iwa ati ise onigbagbo buru toobe ti won ko bikita nipa iwa ati ise eniyan bikose ipolongo esin, iro inu eniyan ibi ni, ajenilese, ika eniyan, atajesile ni opo ti o ngbe Bibeli ati Alkurani, awon woli, alufa, aafa di oluteriba fun owo ati orisa, won di alasotele eke, won a ma to awon emi okunkun lo lati bere fun isotele ohun ti nbo, won fi iro ati aisododo kun ise Oluwa, won ngba agbara okunkun fi se yanu, won nkede esin lai bikita nipa iwa ati ise awon eniyan. Olorun bojuwo aye ni odun 2000 nigbati o pe egberun odun meji (2000) ti Jesu goke re orun, Oluwa dide o si won tempili ati pepe ati olusin to njosin lori pepe re yala eniti o nka Bibeli tabi Alkurani eyiti Oluwa gbenu Johannu so ninu iwe ifihan (Ifi 11:1-2) Olorun ri ogun eniyan to pe niwaju re larin origun merin agbaye, Oluwa wipe nigbati onigbagbo ba wa ninu ile mimo Oun ni won nje eniyan Olorun ni kete ti won ba ti jade iwa won buru ju ti keferi lo.
Olorun ri Nuha ati ebi re nikan soso gbala ni akoko tire, bi e o ba ronupiwada, ogun eniyan pere lo pe niwaju Olohun nigbati o pe egberun odun meji (2000 year) lehinti Jesu goke re orun Oluwa wipe ile aye kun fun eje atipe ori eje ni awon eniyan nrin; alagbara nje alailagbara niya; woli, alufa, imam, alfa di oluwo ni ipade okunkun ti awon alase orile ede si nlo agbara ko seni to le mu mi; e yipada ni Oluwa wi, a ki yoo gbe ojise miran dide fun yin bikose ami Jona (Matt 16:1-4). Oluwa wipe awon eniyan npe Mi ninu ese sibe won ro pe Emi Oluwa wa laarin won, Oluwa wipe ori oke Horebu ti Oun Oluwa sokale si ni ojo Mose si ibiti awon omo Isreali wa je iwon egberun meedogun meeli (15000) pelu bi awon omo Isreali se wa ni mimo fun ojo meta sibe won o le duro niwaju Oun Oluwa ni akoko ti mo sokale . O ni sugbon awon eniyan a wa ninu ese won a tun ma kepe Mi fun iyanu, e yipada ni oluwa wi nitori mo gbe ami Jona dide fun yin lati kede isokan, ironupiwada, igbala okan ati alaafia.
Jesu kansoso na ti nse Oro ti o wa gegebi ofin ninu majemu laelae, Jesu Oluwa kansoso ti Oro ti Baba ti bo inu eje lati fi eje na lele fun araye ki a le ri idariji ati aanu gba nipase eje yi fun awon iwa ati ise eniyan to buru, ki a le ma tele iwa ati ise tuntun eyiti nse ise rere ti o fi lele fun wa. Jesu kansoso na ti nse Oro to wa bi ida ati oko lati jagun lati mu idameta eniyan ti nbo orisa kuro, Jesu Oluwa kansoso na ti nse Oro to wa gegebi eri nikehin ojo yi lati jeri si ohun ti o ti wa siwaju ati lati kede ohun ijinle Olorun, Jesu Oluwa ti nse Oro ti o je Oluwa awon oluwa, Oba awon oba ti araye yoo ri lojukoju.
IGBE FUN IRONUPIWADA
EMI KI NSE OLORUN KRISTENI TABI TI MUSULUMI
Olorun wipe Emi ki nse Olorun Kristeni tabi ti Musulumi bikose Olorun gbogbo agbaye, ohun ti Emi Oluwa se si aye ni ko ye eniyan. E o gbe Bibeli pe mo gba Jesu ni Oluwa pe krisiteni ni mi pelu iwa buburu, ti e si kuna lati tele iwa ati ise rere ti o fi lele. E o gbe Alkurani wipe mo gba Muhammadu ni ojise Oluwa pelu iwa ti o buru, e si kuna lati tele Jesu ti nse Alkurani ti e gbe dani. Oluwa ni mi o ni fi esin yin se idajo yin bikose iwa ati ise yin ti o nbe ni akole niwaju mi gegebi mo se fi iwa ati ise se idajo ni akoko Nuha. Atelewo mi ni mo fi njuwe ohun ti won fi bo aye nigbati o pe egberun odun meji ti Jesu goke re orun (Year 2000) ti Oluwa si wipe ohun ti o tobi ti ko lonka ni sugbon ohun ti o yoku ni mo fi atelewo juwe atipe itansan oorun lo wo aye to nta eniyan lara ti Oluwa si bi mi lere pe ti ohun ti won fi bo aye bayo tan kini mo ro pe yoo sele, mo dahun pe ti itansan lasan ba le ma ta wa lara dajudaju oorun yoo sun aye, e ronupiwada ko di pe Olorun ro ojo ibinu gbigbona lori elese. Olorun wipe ese kinni ati iketa lo jo ara won nitori o je ese aimo Olohun to sugbon iponju ati idajo ese keta ju ikinni lo nitori ese ti awon eniyan da ni ese keta buru ju ikinni lo, begege lo wipe ese keji ti akoko Noa ati ese kerin lo jo ara won nitori mejeji je iwa ati ise eniyan to buru sugbon bi ese kerin se buru to si po ju ese keji lo beeni ki e ma reti idajo nla Olorun ti o ju ti akoko Nuha lo bi e ba ko lati ronupiwada li Oluwa wi.
Awon eniyan npa ara won nitori esin. Bibeli wipe “Iwo ko gbodo paniyan”. Jesu wipe “Enikeni ti o binu si arakunrin re lasan yoo wa li ewu idajo” Matt 5:22. Begege Oluwa so ninu Alkurani pe “Ko to si onigbagbo ododo kan ki o pa onigbagbo ododo kan ayafi ti o ba see esi:……………… Eniti o ba si pa onigbagbo kan ti o si momo, nigbana esan re ni ina; yoo se gbere ninu re: Olohun yoo si binu sii, o si ti se ibi lee, o ti pese iya ti o tobi fun un (surah Nisai 92-93) ko si awawi fun o ni orun pe o pa onigbagbo ododo miran, ronupiwada loni ni Oluwa wi nitori Oluwa kede ohun ijinle re lati mu alaafia wa fun gbogbo eniyan.
Oluwa wipe ohun ti e nse ni ipolongo esin nigbati iwa ati ise yin buru pupo, Gegebi Olorun se wa gbe okan ninu eleri na dide lati ranti ohun ti isaju ati lati jeri si ohun ti isaju pe e dawo ija esin, eleyameya, alaile duro tabi ariyanjiyan lori esin duro bi Olorun se pinnu lati da isokan pada fun eniyan bi e o ba ronupiwada kuro ni ona buburu yin, ki e ma si selo imo ijinle lati wadi Olohun mo, ohun ti awon baba nla wa se to fa ijiya titi di oni, dipo be ki e ma josin si, ma yin, maa juba re, ki e si ma fi ibukun fun oruko re. Olorun wipe emi ni mo fi iboju bo loju ki won mase ri ohun ti mo se.
AFRIKA, PEPE AGBALA TI NBE LODE TEMPILI
Ifihan 11:1 - 2
Eyin eniyan lagbaye bi eo ba yipada si Olohun ti e o si ronupiwada kuro ninu ese yin gbogbo, ti e o si dawo wiwadi Olorun tabi wiwadi ise owo re duro nigbana ni Olohun yoo fi aanu gba yin. Iwo ile Afrika ti Olorun se ileri ikehin ojo yi fun, iwo ti Olorun fi agbara re han ni isaaju, bi o ba yipada kuro ninu iborisa re ati ninu ese re gbogbo nigbana ni Olohun yoo se ohun otun ninu re.
Gbo iwo Naijiria, Oluwa gbe o dide larin ile Afrika ti e jumo ni asotele na lati mu ileri to se ni ainiye egbegberun odun sehin lati enu awon iranse re se, eyiti nse akoko awon keferi (Ifi 11:1 - 8, Isa 19:19 - 25) Iwo ti o ro pe iwo lo nsin Olorun ju sugbon ninu re ni awon ohun ibi, itajesile, ojukokoro ati ohun egbin gbogbo, iwo ti o ngbe orisa ga ju Olorun re, ronupiwada ni Oluwa wi.
​
Iwo ti a gbe dide lati gba awon orile ede kuro lowo ijoba alagbara meji ni eyiti Danieli sotele nipa re (Danieli 8:1-25) ti o si lo nteriba lati ma bebe fun iranlowo dipo ki o gbadura ki Olorun mu akoko re de. Bio tile jepe gbogbo eniyan lo ni ihinrere na, sibe iwo Naijiria Olorun nmura lati si pepe ikehin ojo yi ninu re, eyiti yoo mu ikede isokan ati ironupiwada fun gbogbo eniyan, o si pinnu lati fi iji nla be o wo lati muohunkohun to lodi si tire kuro yaala ernko, emi, eniyan tabi ijoba kan, ati lati ya ile na si mimo. Ronupiwada kuro ninu ise buburu re ki Olorun lemu owo re ni rere wa fun wa. Gegebi Oluwa ti sotele pe akoko ihinrere na yoo le koko pelu alaigbagbo, ki yoo si saaju akoko re jade, ti akoko re ba si to ki yoo lora ni wakati kan (Isa. 19:19-25, Habb. 2:1-4, Sura Maidah 54, Sura Yunusa 19-20, 47-49). Titi di akoko ti Olorun yoo si pepe ikehin yi ati ilana lati fijosin si, alaafia ki o ma bisi fun gbogbo eniyan bi a se nka AWARI akoko yi.