NOTE: Due To Covid 19 and Instruction from the Government, all our services will be conducted online
FAMILY CLINIC 7pm - 9pm
NOTE: Bi o ba di alabukun fun ninu awon eto wonyi mase alaifi oro ranse nipa kiko oro si abala Comment eyiti o wa ni isale patapata tabi ti o ba ni alaaye tabi ibeere, o le ko sibe. Bakannaa o je abala aye lati ki ara wa lakoko yi ki a si ma saalaye bi nkan se nlo lagbegbe wa.

IBI KIKA: OWE 8:1 - 5
TOPIC: ORUKA OBA (KING’S RING)
A o se agbeyewo nipa isele meji ti o sele si awon arakunrin meji kan ti o gba oruka Oba lati wo ise ti oruka Oba nse ati kini won fi se?
Gen 41:37 – 42 – Josefu ba ojurere Olorun pade, eyi si fun ni ojurere lodo Farao. Farao si bo oruka owo re, o fi si owo Josefu. Owe 19:12)
Gen 41:44 – Farao so ise ti oruka na yoo maa se fun Josefu pe yato si oun Farao, gbogbo eniyan to wa ni Egipti, abe isakoso re ni won yoo wa.
Gen 41:54 -57 – A ri pe Josefu lo oruka yi daradara ni akoko to dun ati akoko idojuko agbaye fun awon ara Egipti ati idile re to wa si Egipti.Gen 47:11 -12
Kilo de ti Josefu lo oruka yi daradara?.
(i) Nitori ko ni imo ti ara re nikan, ko ni imo pe ko le dara fun ohun nikan.
(ii) O ni emi idariji fun gbogbo eniyan. Fun awon ara Egipti nitori ara Egipti lo ju sewon, paapa fun awon egbon re to ta si oko eru. Gen 45:4 -5
(iii) O ni emi igbagbe ohunkohun ti enikeni le se fun (Gen 50:15 - 21).
(iv) Ko ni ife ti ara re nikan, o nro ti alaini.
(v) Ko fi ara re si ipo ki oun wa loke, ki awon to ku maa se bi eru labe re.
(vi) Ko ni emi ojukokoro ohun ti aye tabi lati fi ipa di oloro lojiji.
Iru oruka wo ni Olorun fun iwo?.
Matt 24:45 - 47, Qur 6:160
Igbe aye re oruka Olorun ni, ohun gbogbo ti Olorun fun o ni rere ju elegbe re lo, oruka oba ti nse Olorun ni, nje bawo ni iwo se nlo?
Se Satani ko i ti so o di.
(a) Odaju onigbagbo nigbati o rope o si wa loju ona.
(b) Se Satani ko i ti so o di olojukoro onigbagbo.
(c) Se esu o ti so o di alainidariji ati alaigbagbe ese enikeji re.
(d) Se esu ko i ti so o di eniti o mo ti ara re nikan.
(e) Se ifekufe ohun ti aye ko i ti so o di alaini ife enikeji.
(f) Se esu ko i ti ko emi eru ati igberaga si o lokan lati maa beru pe ipinfunni le fa osi
(g) Se esu ko i ti gbe emi ikorira wo o.
Qur 82:9 - 19
MattGe 5:16, 7:21, Qur 2:177 - Gegebi isele (covid 19) to nsele yi se nso fun wa pe opin aye ti de tan atipe o le sele nigbakugba.
Enikeni ti o ba nwa si ile Olorun ti ko gbe igbe aye ti Josefu gbe yi tabi to ni awon iwa ti o lodi si igbe aye rere Josefu, dajudaju o ti nkuro lona ijoba orun laimo, nitori eyi o daraki lati se atunse.
Qur 74:8 - 17, Matt 24:42 - 44 - Paapa ni iru akoko yi ipinfun enikeji re ti o je alaini je pataki nitori a o le so boya igbele ojo merinla (14days) yi ko ni pari ti opin aye yoo fi de. ko ni si aye lati na owo to fi paamo yen tabi ounje to fi pamo to le pin fun alaini.
Tani ha mo boya ise rere kan to o se niyi kopin ko to de, nitorinaa ni emi ipinfunni fun enikeji re alaini lakoko yi.
A o ni so ileologo nu. awon nkan kekeke ti a ko ka si a ma so ni di ero ina oru apadi.