Family Clinic prayer
1. Oluwa ni gbogbo ona ti mo ti si oruka to fun mi lo, Oluwa dariji mi.
2. Oluwa gba mi ma jeki nsi oruka to fun mi lo.
3. Oluwa saanu fun mi ma jeki opin ko de ba iwa keferi lowo mi.
4. Ni gbogbo ona ti mo ti sonu ti mo ro pe mo si wa loju ona Oluwa jowo sanu fun mi da mi pada sodo re.
5. Bere si njewo ese re, ki o si ma bebe fun idariji.
6. Oluwa jowo bi o se saanu fun Israeli ni Goseni sanu fun emi ati ebi mi, ma jeki aarun yi o wole to wa.
7. Oluwa so agbara satani ati awon okunkun di asan lori emi ati ebi mi.
8. Oluwa fun mi ni isegun ni gbogbo ona ninu adura toni.
9. Oluwa bi o ba fa bibo re sehin jowo fi akoko yi se iyanu laye mi atebi mi.
10. Oluwa fi aanu ati agbara re gba ikolo mi pada fun mi lakoko yi.
11. Gbogbo ilekun ti araye ti ti niwaju mi, mo pase e ma si loruko Jesu kristi.
12. Oluwa so emi ati ebi mi di ina ti njonirun
13. Oluwa fi eje re bo emi ati ebi mi, ati awon omo ihinrere yi pelu awon ayanfe re lagbaye.
14. Oluwa nitori aanu re, dawo iji to nja lagbaye yi duro.
15. Oluwa ni iru akoko yi gbe ise iranse wa ro, mase jeki satani ati awon emi okunkun ko ri ise re gbe se.