top of page

Gbogbo ope, ogo ati ola ti Olorun ni fun aanu re lori gbogbo eniyan. Oluwa wipe ijo kansoso ni gbogbo eniyan sugbon won lodi si ara won nitori oro kan ti o gba iwaju Olorun koja, sugbon e ma reti ojo ti Oluwa yoo kede re (AL 10:19-20). Olorun ninu aanu re wa kede ohun ti a nreti yi ni odun 2000  pe Oro ti o gba iwaju oun Olohun koja na ni isele to sele ninu iwe Gen 11:1-8, nigbati oun Oluwa da eniyan lede ru ti Oun si gegun si aye pe awon eniyan o ni gbede ara won mo, sugbon Oluwa tun se ileri pe Oun yoo gbe Joshua kan dide ti yoo we lawani (Seka 3:1-5, AL 10:47-49) nipase ise ti oun Oluwa yoo fi ran olukuluku ti oun Oluwa da lede ru yoo tun josin pelu isokan (Seka 3:10) ki alaafia ki o ma bisi fun gbogbo eniyan bi a se nka awari keta yi.

 

IRAN  KINNI

 

Mo wa ni ori ibusun lekan na ni mo ri owo kan ti o nko kewu si oju orun sugbon ohun ti owo na nko ko ye mi, beni Jesu Kristi Oluwa wole to mi wa, o wipe ki nma bo, mo si dide mo jade tele sita. Nigbati a jade sita, be lo gbe ohun kan le mi lowo ti o dabi igi ti awon to nsare ije nlo (baton). O ni eyi si ni ohun ti ara meje na fohun nigbati angeli alagbara na kigbe ti Oluwa wipe e fi edidi di pe ohun ijinle Olohun (Ifi 10:1-7), eyiti nse ikede isokan ati ironupiwada bi o tile jepe  nisaju ninu irinajo miran ni Oluwa ti gbe opa fitila meje le mi lowo ti o si wipe yoo tan imole si edidi na, lehinna o rin si iwaju die kuro lodo mi,  O si ngoke lo si orun titi nko fi ri mo.

 

OHUN IJINLE OLOHUN APA KINNI

 

Angeli keje na fun ipe ni odun 2000, Oluwa si wipe, Emi ki nse Olohun esin yala kristeni tabi musulumi bikose Olohun gbogbo agbaye atipe ohun ti oun Oluwa se si aye ni ko ye awon eniyan. Oluwa wipe se ni awon eniyan fi esin boju lati ma wu iwa buburu gbogbo. O ni oun Oluwa ki yoo fi esin na se idajo,  bikose iwa ati ise wa ti o nbe ni akole niwaju oun Olorun. Ka nipa re daradara ninu  AWARI AKOKO ati ikeji ti nse AMI JONA.

 

Angeli Oluwa na so ninu iwe Ifihan pe “Igba ki yoo si mo sugbon ni ojo ohun, nigbati angeli keje yoo ba fun ipe nigbana ni ohun ijinle Olohun pari, gegebi ihinrere ti o so fun awon iranse re awon woli (Ifi 10:6-7). Mase gbagbe pe atelewo ni mo fi njuwe ohun ti Oluwa fi bo aye nigbati o pe egberun meji (2000) ti Jesu goke re orun, ti Oluwa si wipe ohun ti o tobi gan an ni sugbon ohun ti o yo ku ni mo fi atelewo juwe atipe itansan oorun lo wo inu aye na. Oluwa wipe, ti ohun ti Oun fi bo aye ba yo tan kini mo ro pe yoo sele? Mo dahun pe ti itansan lasan ba le ma ta wa lara dajaudaju oorun yoo sun inu aye ni. Eyin eniyan lagbaye, e ronupiwada ninu iwa buburu, eyiti e fi esin boju to ge,  ki e le ri isimi fun okan yin nikehin.

IRAN KEJI

    

             Ni odun 2003, mo wa ninu iporuru okan pe bawo ni mo se fe kede ohun ti Oluwa fi ran mi yi. Ninu iporuru okan yi ni mo wa ti Oluwa wole to mi wa. O si ni ki nwo iwaju, lojiji ni mo wo inu emi lo, mo ri igi kan ti o rewa ti o kanle laye ti o si tun kanle lorun, ewe re rewa pupo, o si te si gbogbo oju orun.

 

Mo ri okunrin agbalagba meji ti won duro si idi igi na, meji ninu ewe ori igi yi si wo si iwaju won, bi mo se nwoye kini itumo eyi, tani awon eniyan Olorun meji yi? Beni mo gbo ohun lati inu orun wa wipe igi ti o kanle ni aye ati ni orun yi ni pe ase Oun Olohun kanle laye,  O si tun kanle ni orun. Okunrin meji ti mo ri yi ni woli Mose ati woli Muhammadu, itumo ewe ti o wo si iwaju won ni pe ewe kan ko ni jabo lori igi ko sehin Oun Olorun, ise iranse ti won se ko sehin oun Olohun. Ibiti oun Oluwa fe ki won mo nipa oun mo ni won mo, ohun ti Mo se si aye ni ko ye awon eniyan. Mo ti so fun o pe ko si iyapa ni orun atipe emi Olohun ki nse Olorun kristeni tabi ti musulumu bikose Olorun gbogbo agbaye nitorinaa iwo ni a tu edidi ohun ijinle yi fun nikehin ojo yi, tesiwaju lati ma kede ohun ti mo fi ran o.

OLORUN KI NSE OLORUN ESIN

 

Fun iwo ti o nse ariyanjiyan nipa esin tabi ja ija esin tabi pa enikeji nitori esin, ko ha ye ki o ronupiwada loni, ranti pe o duro niwaju Olorun  lati jihin ise re ni ojo kan nitorinaa o dara ki o ronupiwada loni nitori ibinu Olorun nbe lori awon apayan. Nigbati Mose pelu awon omo Isreali sise iranse nipa ogun, o je ohun ti Olohun fe ni akoko na (Eks 23:20-30)  Sugbon nigba to ya Olohun ni ipinnu miran pe “Enikeni ti o binu tabi sepe fun arakunrin re yoo wa ni ewu ina orun apadi (Matt 5:21-22) lai ti wa so pe o pa eniyan.

 

Nigbati Annabi Muhammadu wa sise iranse nipa ogun be gege lo je ohun ti Olorun nife si ni akoko na. Oluwa so ninu Alkurani pe “A pa ogun jija  ni ase fun yin” AL (2:216, Ifi 9:13-21) Sugbon nigba toya Olorun ni ipinnu miran pe “Eniti o ba pa onigbagbo ododo kan ti o si momo nigbana esan re ina, yoo se gbere ninu re; Olorun yoo si binu sii, O si ti se ibi lee, o si ti pese iya ti o tobi fun un (AL 4:93). Nitorinaa o dara ki o ronupiwada loni ki o ma ba jebi lorun nitori ija esin.

bottom of page