top of page

OLORUN TOBI JU O LO, ONIMO IJINLE

Ronupiwada loni iwo onimo ijinle ti o nfi ojojumo wadi ise owo Olohun, nse loro re dabi ikoko ti o nwadi amokoko, nibo ni amokoko ti ri yepe, omi ati ohun gbogbo ti amokoko lo lati fi mo o; beni ko gba amokoko ni iseju kan ti yoo fi wo ikoko danu. Nje o le ka irawo oju orun, nje o le da osupa duro ko ma yo, tabi se o le mu oorun wo lojiji? Ti o ko ba le se, a je pe Olohun tobi ju o lo iwo onimo ijinle. O wa imo ijinle titi nipa ise owo Olorun ko jeki o mo ona lati sin in, nje o le se ko ma ku mo laelae? Ti o ko ba le se, a je pe Olorun tobi ju o lo iwo onimo ijinle. Ti o ba je pe ohun gbogbo ti Olohun da lo ye o, ti o si le soro nipa re, o ye ko le so fun iku pe ko gbudo wa, sibe ko seese fun o, eyi tumo si pe Olorun tobi ju o lo,iwo onimo ijinle. Olohun wipe erupe ni wa, a o si pada di erupe, nje mo wi fun o, ti imo ijinle re ko ba le da o duro ko ma pada di erupe, a je pe Olohun tobi ju o lo,  iwo onimo ijinle, o wadi ise owo Olorun titi, o so igbagbo sonu pe ko solorun, nje to ba je beni o ye ko le pase fun aburo iku ti nse oorun sisun ko ma wa, nje o ri pe Olorun tobi ju o lo, iwo onimo ijinle.  Kilo  de  ti o kuku fi imo ijinle re sile, ko ye wadi Olohun ati ise owo re mo. Tani onimo ijinle? Olorun ha ko, Oba ti o gbe aye kale ti ko je ko subu, to si gbe orun duro laisi opo, ohun ti o ye o ni pe ki o lo ma josin si, ki o ma gbega.Yin fun ohun ti o se ati eyiti ko I ti se ati eyiti o nbo wa se nitori ise owo re awamaridi ni, yoo si dara fun o.

   

NAIJIRIA NI OJO WO NI IWO O YIPADA SI OLUWA

           

Orile ede ti sinsin Olohun po ti ese si tun po bakanna nigbawo ni iwo o yipada si Oluwa. Iwo Afrika, eese ti iwo fi nduro de akoko ti Olorun yoo lu o bole ki o to yipada si Oluwa, iwo ti Isaiah sotele fun pe “Oluwa yoo si lu Egypti bole yoo si mu lara da: won o si yipada si Oluwa, oun o si gbo ebe won, yoo si mu won larada (Isa 19:22). Iwo Naijiria bio tile jepe Olohun se ileri lati mu ese re kuro ni ojo kan (Seka 3:9) iwo ha nduro de akoko ibinu re ko to ronupiwada? Nje owo Olorun ha le mu alaafia wa fun ohun egbin, idoti pelu inira gbogbo ti o kun inu re?  Eniti yoo gbe igbe aye ododo ninu re yoo ni iponju ati inira, nje inu Olorun ha le dun lati ri opo ti o tori iponju ati inira fi igbe aye ododo sile tabi fi ona si ijoba orun (Alujona) sile nitori iwa ibaje gbogbo ti o kun inu re. Eniti o pinnu lati je olododo ninu re lo nla inira, aini ati iponju koja ayafi awon ti o setan lati gbe ninu aisododo ati ese. Naijiria ni ojo wo ni iwo o yipada si Oluwa nitori ibawi Olorun dara ju ibinu Olohun lo. Ki alaafia ki o ma bisi fun gbogbo eniyan bi a se nka Awari keta ti nse OHUN IJINLE OLORUN APA KINNI..

Awari
bottom of page