ORO TI O RUJU ATI EYITI O YANJU
​
Oluwa so ninu surah Imrana ese keje pe “Olorun lo so oro (Tira) na kale fun o; ninu re awon iran (Revelation) ti o yanju nbe, awon ni gbongbo ihinrere na ati pe awon miran wa ti o ruju, awon ti iyapa (igunri) nbe ninu okan won, won a tele eyiti o ruju ninu re lati fi da rogbodijan sile ati lati fun ni itumo tire. Beni ko si eniti o mo amojinle itumo re gan ayafi Olorun (AL 3:7). Die ninu oro ti o yanju ti Bibeli ati Alkurani fidi re mule.
​
(1) Olorun ni ki a mase dese, ki a si ma jewo ese wa nigbati a ba dese. Iwe Owe 28:13, Isa 55:7, Esek 18:21, Al 2:160, 6:120.
(2) Iwa Mimo AL 74:4-5, 87:14, 91:9, II Kor 7:1, Heb 12:14, I Pet 1:16.
(3) Ise owo re ni yoo gbe o wo ijoba orun tabi wo orun apadi (Alujona tabi Ina jahanamma) AL 4:124, 2:177, Gen 6:5-6, Isa 3:9-10, 40:10, Matt 24:37-39, Luk 12:47, Ifi 22:12.
(4) Nitori eyi Olorun nbere fun ise rere re AL 6:160, 22:14, 28:83-84, Matt 6:16-20, 12:35-36, I Tim 5:24-25, Jak 4:17.
(5) Lila owo si ise Olohun ati fifun enikeji re Owe 3:9-10, 28:27, LK 6:38, AL 2:274, 4:36, 57:11, 18.
(6) Adura ni ebo onigbagbo AL 2:186, 7:55, 40:60, Isa 55:6, Matt 6:6, 7:7-8.
(7) Iwo ko gbodo sin Olohun miran tabi orisa AL2:221, 5:90-91, 10:18, Eks 20:3-5, Matt 6:24, Joh 4:23-24.
(8) A ti fifun eniyan lati ku lekan soso Gen 3:19, Heb 9:27, AL 4:18, 21:35.
(9) Igbasoke Matt 24:40-41, I kor 15:51-52, I tess 4:15-17, AL 74:8-10, 78:17-20.
(10) Ojo idajo Matt 11:22, 25:31-33, Ifi 14:7 AL 2:48, 58:17, 78:38-39.
(11) Ajinde Oku Al 4:159, 20:124, 28:39 - 41, 39:60, 60:, Matt 22:23 -30, Joh 5:28 -29 Ise 24:15.
(12) Emi Mimo Joel 2:28-30, J0h 14:26, AL 16:102, 70:4.
Ti a ba wa nso nipa oro ti o ruju, okan ninu re ni Tani Jesu nse. Ninu Awari kinni, Oluwa so ninu orun pe Bibeli ti o nbe ni owo mi otun ni Jesu, Alkurani ti o nbe ni owo mi osi ni Jesu ati pe Jesu yi ni Emi OGA OGO fi ropo ara mi si aye pe,Oluwa ti gbogbo eniyan yoo ri lojukoju ni yi. O wipe ORO ni, Oluwa ni.. Oluwa fidi re mule ninu iwe ifihan pe Oro ni, Oluwa ni. “Mo si ri orun si sile, si wo esin funfun kan eniti o joko si ori re ni a npe ni olododo ati oloto, ninu ododo li o nse idajo ti o si njagun…A si wo ni aso ti a te bo inu eje, a si npe oruko re ni ORO OLORUN…O si ni lara aso re ati ni itan re oruko ti a ko OBA AWON OBA ATI OLUWA AWON OLUWA (Ifi 19:11-16).
​
Oluwa tun fidi re mule ninu Alkurani pe Oro kansoso ti nse Jesu Oluwa ni yoo je eleri tako eniyan ni ojo idajo. “Atipe ko si enikeni ninu awon ti o gba oro Olohun gbo (Onitira) ayafi ki o gbaa gbo siwaju ki o to ku, ti o ba di ojo ajinde yoo je eleri tako won (AL 4:159). Jesu Oluwa so siwaju ninu iwe Johannu nigbati o nso nipati agbo ti awon ara antioku (ise 11:26) pada pe ni kristeni pe “Emi ni oluso aguntan rere: Oluso aguntan rere fi emi re lele nitori awon aguntan (Joh 10:11). Sugbon nigbati o kan agbo ti o pada di musulumi gegebi ilana ti Oluwa fun Abrahamu (AL 2:127-132). Oluwa so ninu iwe Johannu bakanna pe “Emi ni awon aguntan miran ti ki nse ti agbo yi, awon li emi ko le se alaimu wa pelu, won o gbo ohun mi; won o si je agbo kan oluso aguntan kan (Joh 10:16).
​
E beru Oluwa ki e si ronupiwada ninu ese yin, ki e le ni ibujoko ni ijoba re. Esin mi lo dara ju tabi esin mi ni Olorun tewogba ju nigbati Olohun mo pe, e fi esin yi boju nigbati ise owo yin buru toobe ti Olorun won Tempili ati pepe ni odun 2000, ti o si gbe odiwon le ise owo awon olusin to njosin ninu tempili ati lori pepe lorigun merin agbaye yaala awon ti o ngbe Bibeli tabi Alkurani gegebi o ti so ninu iwe ifihan 11:1-2. Olorun si ri ogun eniyan (20 people) to pe ni gbogbo ona won niwaju Re, o wipe nigbati e ba wa ninu ile mimo oun Oluwa le nje onigbagbo sugbon ni kete ti e ba jade iwa yin buru ju ti keferi lo. Ronupiwada ki iku tabi opin aye ko to de ba o, nitori tani eniti o le gbe Olorun ni ija.
IRAN KETA
Angeli Oluwa to mi wa, o si mu mi rin irinajo wo inu orun, mo si nwo ite kan ni oke ti gbogbo ile (ground) re je kiki wura. Ni ori ite yi ni mo ri aga iwasun (pew) kan ti o je kiki wura, niwaju aga iwasun na ni mo ri ilekun kan ti o je ide ati wura sugbon ko si ogiri tabi yara beeni ite na teju ti mi o si ri opin re. Lehinna mo ri Jesu Kristi wa siwaju aga iwasun na pelu iwe kekere kan lowo. O si nka gbogbo ohun ti o wa ninu re sugbon mi o gbo ohun ti O nka, nigbati o ka tan o wo inu ilekun na lo, mi o si ri mo. Lehinna mo ri eniyan Olorun kan pelu iwe kan lowo wa si ori aga iwasun na, Oun na ka tire, O si tun wo inu ilekun na lo.
​
Lehinna mo ri ojise Olohun miran, o ka tire, o si tun wo inu ilekun na lo, lehin eyi ni ojise Olorun kan tun wa eleyi je apari, Oun na si ka tire, ki o to kuro nibi aga iwasun na, mo bere lowo Angeli ti o mu mi rin irinajo na pe, lehin Jesu Kristi Oluwa tani awon meta yi? Kini ohun ti won nka ti mi o gbo atipe kini ohun ti won nka wa fun? O dami lohun pe Mose, Elijah ati Elisha ni awon woli ti mo ri yi, O tesiwaju pe Jesu Kristi Oluwa wa pelu awon woli meta yi ti won le pase ohunkohun ni aye ko si fidi mule ni won njihin ise won fun OGA OGO.
Mo wa bere pe sebi awon woli wonyi sise iranse saaju Jesu Oluwa wa? Angeli na damilohun pe mo gbagbe pe, a ti ko pe ‘Ki aye to wa Emi ni ati ki a to da awon oke Emi ni” O tesiwaju pe ti awon woli meta yi ba le jihin ise won fun OGA OGO, lo so fun awon ojise Olohun pelu gbogbo eniyan pe olukuluku ni yoo jihin ise re ni ite idajo.
O JIHIN ISE RE, IWO ALAGBASE
​
Iwo alagbase,ti o sa si abe oro Olorun to wipe “ki a mase dani lejo ki a ma ba da o lejo” Emi o da o lejo sugbon mo nkede fun o ise ti a ran mi si o, iwo alagbase ti o nsi agbara ti Olorun fun o lo, ronupiwada loni, iwo alagbase ti ko le duro de akoko Olorun ti o lo ngba agbara okunkun nitori iyanu, o jihin ise re, iwo alagbase ti nwi nigbati Olohun ko wi yaala Alufa, Aafa, Woli tabi Imam o jihin ise re. iwo alagbase to so ojo ajodun tabi moulud di owo sise yipada, otito ni orun apadi nbe. Oro Olorun wipe “Ife owo yi o po nikehin ojo” nipa eyi e so isoji, apejo adura, ajodun ati moulud di owo sise. Oro Olohun ko mu ibukun wa mo bikose omi inu ora (sachet water) ati ororo (anointed oil) ni ohun ti e fi ntaja pelu awon asotele nlanla gbogbo ni ojo ajodun ati awon eto miran ti e nse. Ko si ohun ti e mu wa saye ko si ohun ti e o mu lo, I ba dara ki e ronupiwada nitori Oluwa nko ise owo yin sile.
E yipada, eyin alagbase ti e so ara yin di Olorun nitori eyin lo mo iru iyanu ti o to si olukuluku to njosin, awon to lowo lowo iyanu nla, awon ti ko ni pupo iyanu die, awon ti ko ni rara ko je nkankan nile Olohun. Eyin alagbase, e beru Olorun, e ti gbagbe pe obinrin opo ti o fi ore ti o kere ju sile ni Oluwa wipe ore re se itewogba ju nitori ohun gbogbo ti o ni lo fi sile sugbon awon olowo nla ninu opo ti Olorun fun won ni won ti mu die wa.
Lehinti e ba fi etan pelu itan iyanu orisirisi ti ko sele gba oro (wealth) lowo awon olujosin tan, lehinna e o so ara yin di Sakeu agbowode ti o fi abo (Half) ohun ini re fun awon talaka lehin to ti fi esun eke gba lowo awon eniyan nisaju. E beru Oluwa nitori ojo ti e o dake ti ko ni si atunse fun awon ohun ti e se gbogbo, opo ohun ti e nwasun re fun awon olujosin pe ki won ma se ni won nba lowo yin, ranti pe oro Olohun wipe lati ori pepe ni idajo yoo ti bere. Ranti o iwo alagbase, o jihin ise re.
IRAN KERIN
Oluwa mu mi rin irinajo lo si adugbo kan ninu emi, mo ko Awari pelu Ami Jona dani lati pin fun awon eniyan sugbon mi o ri enikeni lati fun nitori ile ijosin nla kan wa ni adugbo na ti ainiye eniyan kun inu re, awon ti o wa ninu re yoo to egberun lona ogoji (40000). Awon olujosin gbe oko (car) olowo iyebiye wa si ile ijosin na, bakanna ni awon akorin (choir) won nkorin bi igbati orun nsokale. Mo tun ri awon ojise Olorun nlanla to kun ori pepe won. Bi mo se nkoja lo ladugbo na, mo ronu pe awon eniyan wonyi o nilo oro Olorun ti mo ko dani nitori ti nba wo ore ti Olohun se fun won nipa ipo olowo ti won wa, mo tun ronu pe awon akorin won paapa nkorin bi ti awon angeli, awon Alufa won je awon ojise Olorun nlanla ti won ni imo pupo nipa oro Olohun, mo ni awon eleyi ko ye fun awon ti nba kede ironupiwada ati igbala okan fun.
Nigbati mi o ri enikeni fun ni oro Olohun ti mo ko dani mo pehinda lati ma lo beeni mo ri eniyan Olorun kan ti o ti rekoja ti o ntele mi lehin ti o si nkigbe igbala, igbala…..Mo ni kini o kan emi ati baba yi sugbon gbogbo ibiti nba ya si lo nyasi, o si nkigbe tele mi lehin. Nigba toya mo duro pe kilo de? O bere ibeere lowo mi pe ile ijosin ti mo koja yen kilo de ti mi o fun won ni oro ikede ironupiwada ti Oluwa fi ran mi? (Awari/Ami Jona). Mo dahun pe won o nilo re, o wi fun mi pe bi gbogbo ijo ti mo ri yen se tobi to ti opo olujosin kun inu re pelu oko nlanla ti mo ri yen, ko si eniti o ni igbala latori Adari titi de ori awon akorin ati awon olujosin nitorinaa lo kede igbala fun won. Mo ni kilo de? O ni lo kede ironupiwada ati igbala fun gbogbo eniyan, beeni Oluwa wipe irinajo ti mo fe mu o rin niyi. ‘
NJE O TI NI IGBALA
Igbala je iyanu ti o soro lati ri gba, otito ni oro Olohun so wipe “ko si ohun ti o soro fun Olorun lati se” ko soro fun o lati ri iyanu gba lowo Olorun, awon iyanu bi: owo, oro, ola, awon iyanu bi ki afoju riran, alaisan ri iwosan, odi ko soro, aditi ko gboran, agan ko di olomo, eniti ogun nja ko ri isegun ati beebe lo sugbon iyanu nla ti o soro lati ri gba ni igbala nitori lati ronupiwada kuro ninu ese isoro lo je fun opolopo ti o nsin Olohun loni, lati se ife Olorun isoro lo tun je fun opolopo. Ti o ba ronupiwada kuro ninu ese ti o si ngbiyanju lati se ife Olorun, ni igba gbogbo lo npade tabi ri awon ohun ti o le gba igbala sonu lowo re, bi o je owo, yoo je oro, okunrin, obinrin tabi ifekufe aye miran, tabi awon idojuko bi iji, isoro, ogun, iponju, aini, inunibini ati beebe lo. Bawo lo se fe gbe larin awon eniyan ti o setan lati fi iwa ati ise won gba igbala sonu lowo re, ayafi ti o ba pinnu lati jogun ijoba Olorun.
​
Jesu Oluwa wipe yoo rorun fun ibakasie lati wo oju abere ju fun oloro lati wo ijoba orun, eyi ntoka si pe ki nse imura re tabi o ngbe Bibeli tabi Alkurani lojojumo lati se afihan pe onigbagbo ni o lai se ife Olohun ti o nbe ninu oro re, ko tile nse nitori mo nko orin tabi nitori iwo lo le se iwasun / waasi ju tabi kirun/ gba adura ju lo se le wo ijoba orun bikose nipa igbe aye iwa mimo ti o pinnu lokan re lati gbe. Mase gbagbe, Olorun o fi esin se idajo laye Nuha, ko fi imura won se bikose iwa ati ise won to nbe laakole niwaju re be gege ni Oluwa wipe oun o ni fi imura yin se idajo, yaala imura ti awon to ngbe Bibeli tabi ti awon Alkurani bikose iwa ati ise yin ti o nbe ni akole nitori loni imura je okan ninu ohun ti a fi nda iru onigbagbo to je mo. Tete wa igbala ri loni ki o ma ba je osoosu ni o ma faye re fun Olorun.