MESSAGE (IWASUN)
THEME: NJE GBOGBO EBI LE WO IJOBA ORUN ?
Ibere nla ni ibeere yi sugbon a o dahun re pelu imo ati oro Olorun.
Idahun si ibeere yi je ona meji.
Beeko ati Beeni, sugbon a o koko wo Beeko ni ose yi.
Lati rin irinajo si ijoba Olorun, olukuluku ni yoo ru eru ara re. Areru kan ko ni ru eru elomiran.
Matt 24: 40- 41, Jesu salaye pe eniyan meji a ma lo, a o mu okan, a o si fi ikeji sile, eyi tumo si pe, eniti o ba se ife Olorun ninu ebi nikan lo lewo ijoba olorun. Eyi tumo si pe eniti o ba se ife Olohun ninu ebi nikan lo le wo ijoba orun.
Eyi ni omo ko fi gbudo faye gba awon obi re lati le soo di ero orun apadi.
Nigbati baba tabi iya re ba ni ko se ohun to lo di si ife Olorun, o ko gbodo se.
Iya o gbudo so pe, ko ba oun paaro. Tabi nitori awon obi re nba awon eniyan kan ja, iwo na lo darapo mo won, eyi o dara o le gbe eniyan wo oru apadi tabi awon obi re nba eniyan kan yan odi, iwo na si lo nsebe, o nsilekun ijoba orun apadi fun ra re. Iwo nilati rin irinajo igbala tire nitori olukuluku ni yo gbere ise re.
Qur 31:14-15- Olorun oba fiye wa pe ti obi ba fe towo re bo ese, o nilati yera fun won ki o si ko fun won.
Be gege na lo ri fun awon obi nitori olukuluku ni yoo gbere ise re.
Obi o gbudo faye gba omo lati towo re bo inu ese paapa awon iya tabi baba to nba omo bo ese mole. Baba tabi iya to ngbe sehin omo pelu iwa buburu ko le sai sileku orun apadi sile funrare.
Qur 64:15, Olorun tile so pe adanwo ni omo je ti a o ba sora, a le tipase won wo orun apadi.
Qur 18;74, 80-81, Ninu irinajo Angeli ati Mose, Olorun pa omokunin kan nitori ko ma ba so awon obi re dero ina jahannama, eyi fihan pe ko si awawi pe omo lo so mi dero orun apadi.
Irinajo ijoba orun olukuluku ni yoo ru eru ara re.
Eyi ni oko o fi gbudo faye gba iyawo lati towo re bo ohun ti ko dara nitori o fe te iyawo lorun. Tabi iyawo to fe te oko lorun, ti o wa npelu oko se ohun to buru, awon mejeji nsilekun orun apadi fun ara won ni.
Matt 22: 23-31, Jesu wipe ni ijoba orun, ko si ohun to nje oko, aya tabi omo nibe.
1Kor 10:12, Itan Anania ati Safira fi yewa pe oro igbala olukuluku ni yoo ru eru ti ara re, aijebe iyawo tabi oko ti o je eni igbala le tipase oko tabi aya wo orun apadi ti a o ba kiyesara.
Bi o se je ototo la waye ototo na la o duro niwaju ite idajo nikehin. To ba je pe Safira ko darapo mo oko re nigbati o de iwaju ite idajo ti aye niwaju peteru, yoo bo lowo iku ojiji aitojo.
Ise 5:1-10, Matt 25:32.
Kini o le mu Safira darapo mo oko re Anania lati dese?
1. Ki oko re ma ba binu.
2. Ki alafia le wa ninu ile re.
3. Ki alabagbe ma ba gburo won nigbati oko re ba nbinu.
4. Boya nitori ife to nbe larin won.
5. Nitori oro Olorun so pe okan niwa a ki nse meji, a gbudo maa fohun sokan lori ohun gbogbo.
6. Nitori oro Olorun lo ni ki nteriba fun oko mi ninu ohun gbogbo.
Kini o le mu Anania darapo mo iyawo re dese ?
1. Lotito oun ni olori ile sugbon o le je pe nitori ki iyawo re ma ba binu ni.
2. Ki o le te iyawo re lorun.
3. Nitori ki ile re le ni aalafia, nitori ti o ba lodi si imoran iyawo, o le ma roju iyawo mi nile.
4. Nitori o ni ife iyawo mi.
5. Tabi ti o ba ko lati se, o le pe iyawo re loru ko sope rara ko saye.
Obinrin le so pe ti o ba ko gbogbo owo na sile, kini a o ma je, ile si le gbona lotito. Sugbon ati okunrin ati obinrin, a ko gbudo faye gba aalafia, Itelorun, Ife to le mu wa padanu ijoba Olorun.
Ifi 22:12, Oluwa ko tile so pe oko ati iyawo yoo gba ere ise won sugbon Oluwa wi pe olukuluku ni yoo gba ere ise re, nitori eyi ise igbala olukuluku di owo olukuluku.
Ko si eniti esu ko le yalo lati dena ijoba orun, bi o se lo Efa lati le Adamu jade ni ijoba orun ti aye, eyi la ko fi gbudo faye gba ohunkohun lati odo iyawo tabi oko to le gba ijoba orun lowo wa. Qur 59:16
O dara lati ni nkan wonyii ninu igbeyawo tabi ebi wa
1. Ife.
2. Alafia.
3. Igbora eni ye.
4. Oko nilati te iyawo re lorun be gege aya nilati te oko lorun.
5. Iteriba fun oko.
6. Ifoye ba iyawo gbe.
Sugbon nigbati awon nkan wonyii ba fe ran wa lo si orun apadi, a gbudo wa ijoba Olorun, ko to kan awon nkan wonyii. Matt 6:33
Jesu Kristi paapa so fun wa lati ko ni ife Olorun wa ki o to kan enikeji ti nse oko tabi aya tabi omo tabi elomiran. Matt 22:37 - 39
Nitori ti opin aye ko ba i ti de, gbogbo wa ko le ku ni ojo kan na. Ti o ba ri be, iwo to fe te oko tabi iyawo lorun, ti o si darapo pelu re ninu ese tabi iwa buburu, ranti ti o ba je oko lo koko ku ti iyawo si lo ronupiwada lehinna nko tabi tabi to ba je iyawo lo koko ku ti oko si lo ronupiwada lehinna. E jeki a saaro nipa eyi ki a si seto igbala okan wa lasiko. Heb 9:27.
Nibi a ko se mo akoko ti opin yoo de, sugbon ti a si nri awon ami re bi corona virus (covid 19), Matt 24:7. E jeki a mura sile nipa siseto igbala okan wa.
Nitorina beeko ni idahun si ibeere na nipa awon alaye wonyii, a o ma wo idahun beeni ni ose to nbo ti Jesu Kristi ba fa bibo re sehin.
Adura: Oluwa ni onakona ti mo ti darapo mo oko tabi aya tabi omo dese Oluwa dariji mi
(2) Ohunkohun to wa lowo mi to le mu mi padanu ijoba orun Oluwa gba lowo mi.
San Idamewa tabi Ore re si awon account number yi, tabi ki o fi pamo di igbati isin yoo wa.
Ore tabi Ore Idupe Osoosu: Eko Bank: 3511312706
Idamewa……Access Bank :0093365322 Adewumi Nuru Joshua
Adura ipari isin: Gbogbo eyin okan to darapo mo isin oni ati gbogbo omo ihinrere yi lapapo Oluwa yoo bukun fun yin amin.
Fun awon ti o fe ri mi, ma wa ninu ile ijosin ni agogo merin (4pm) oni Sunday 5/4/2020