Ope ni fun Olorun to ni gbogbo ogo ati agbara nikawo. Oba to feran eda ise owo re, ti ko si fe ka parun. Oba to fi ife re han si wa nikehin ojo yi lati gbe okan ninu eleri re dide lati kede ironupiwada fun gbogbo eniyan (Matt 16:1-4, AL Maidah 54). Mo ti kede re ni isaju ninu Awari ti akoko pe Olohun wipe oun o da esin ati pe Oun Olorun ki nse Olohun Kristeni tabi ti Musulumi pe oun ti Oun Olohun se si orile ede alaye ni ko ye awon eniyan atipe nse ni e fi esin boju nigbati ise owo eniyan buru ju ti akoko Nuha lo. Oluwa ni Oun ki yoo fi esin se idajo bikose iwa ati ise eniyan to nbe ni akole niwaju Oun Olorun. Ki alaafia ma bisi fun wa bi a se nka Awari keji yi (Amin).
​
IRAN KINNI
Mo ri Angeli Olorun alaye kan ti o gbe iwe nla kan lowo, o si mu mi lo si ipekun aye yi, mo si ri o je oke lo yi ka, mo bere pe sebi won ni omi lo yi aye ka, o damilohun pe rara oke lo yika. Mo si ri pe ko tobi pupo ju ohun ti eniyan le ma wo gbogbo re lo, mo wa bere pe se inu ibi kekere yi ni oyinbo ati eniyan dudu ngbe? O damilohun pe beni awamaridi ise Olohun niyen,
Mo wa tun bere lowo Angeli na pe sebi won ni egberun odun meji lehin iku Oluwa wa ni aye yoo pare, o damilohun pe oun ko mo igba ati akoko, o ni beni emi na ko mo igba ati akoko. O oni sugbon ki ngbe oju soke wo ohun ti Olorun fi bo aye bo se nipon (tickness) to. Mo dahun pe ohun ti mo ri nipon bi atelewo mi, o dudu bi oda (Tar) ti a fi nkun titi (road) o si nyo. Angeli na tesiwaju pe ohun ti mo ri yi, ohun ti o tobi ganan ni sugbon ohun ti o yo ku ni mo fi atelewo juwe yi.
O wi fun mi pe ki ngbe oju soke kini mo tun ri? Mo dahun pe mo ri itansa oorun (ray of sun) ti o wo inu aye bi igbati orule ile ba njo ni oju iso (nail) ti itansan oorun si wo inu ile. Angeli na dahun pe beeni Itansan oorun nikan lo wo inu aye ti o nta eniyan lara. Emi na tesiwaju pe ti a ba sa nkan sinu re o ma ngbe, Oun na dahun pe itansan oorun ni. Angeli na wa bi mi lere pe bi ohun ti won fi bo aye ba yo tan kini mo ro pe yoo sele?. Emi na dahun pe ti itansan oorun ba le ma ta wa lara dajudaju gbogbo oorun yoo sun ile aye ni, o dahun pe beni. Angeli na so fun mi pe ki ngun ori oke ti o wa niwaju mi ki nsi wo isale lati wo ohun ti awon eniyan nse ni orile aye. Lehinti mo gun ori oke na tan ti mo wo isale, mo dahun pe mo ri ile aye kun fun agbara eje (full of blood) atipe ori eje ni awon eniyan nrin, mo ri awon eniyan won njaye ijekuje ati ifekufe gbogbo, eniti nse agbere, pansaga, eniti nse ebo to nbo orisa, eniti njale, omuti ati awon ese miran.
O tun bi mi lere pe kini mo tun ri? Mo dahun pe mo ri awon to npa ara won nitori esin, mo ri Alufa to lo ifunpa, mo ri Aafa to lo igbadi ati beebe lo. Mo wa fi itara bere ibeere pe kini yoo gbehin awon eniyan wonyi? O dahun pe nitori eyi la se gbe o dide nikehin ojo yi lati lo kede ironupiwada fun gbogbo eniyan, o ni eyi ni ami Jona ti a o fi mo pe opin de tan.
Lehinna angeli na tun wi fun mi pe ki ngbe oju soke kini mo tun ri? Mo dahun pe mo ri oju ona kekere kan ti won de enu re ti ko gba ju owo omo kekere, o wipe beni oju ona ti awon ti o ba nbo ni aye ngba wa niyi, oju ona kansoso ti awon to ba njade laye ma ngba jade, mo ni eyi ko gba eniyan lati koja, o dahun pe awamaridi ise Olorun ni yen, o ni ki nje ka jade, bi a se jade, mi o mo beni mi o le so. Lehinti a jade tan ni mo ri ile aye yi o dabi agba (cask) ti awon elepo tabi olomi fi ngbe epo tabi omi, won gbe si ori ile ti o teju ti ko si lopin, mo dahun pe Olorun ku ise re.
Ni ori ile (Land) tuntun miran ti a jade si yi, awon ile miran wa ti won ti se ipinle (foundation) re , awon kan wa ti won ti ko ile si ori re. Angeli yi mu mi lo si ori ile ti won ko i ti ko ile si ori re. Bi a se nrin ori ile yi beni Angeli yi ju aworan (Picture) arabinrin kan sile, mo daruko arabinrin na pe mo mo ni Akure, o wi fun mi pe o tun ni ile miran si isale. Mo wa bere pe ile temi nko? O damilohun pe Oun ko mo boya mo da owo ayafi ti oun ba bami wo iwe owo oun. Bi o se fe ma si iwe na beni arakunrin kan de si ori ile tire lati wa sise. Angeli na wi fun mi pe a ko fun enikeni lase lati ri oun tabi gbo oro oun ayafi emi nikan nitorina ki nje ki a ma lo, bi a se nlo o wi fun mi pe ki nlo kede oro na fun gbogbo eniyan.
​
AMI JONA (Matt 16:1 - 4)
RONUPIWADA NISISIYI
Eyin eniyan lagbaye bi e o ba ronupiwada nikehin yi nigbana ni Olohun yoo fi aanu gba yin. Olorun wipe opo eniyan lo ti mo pe oun Olorun nbe laaye, sugbon olukuluku nse ife inu ara re, e nlo ile aye bi igbati e o ni kuro ninu re, e nlo ile aye bi igbati e o ni jabo ise ti e se ninu re. Lojojumo le nta eje sile nipa eniyan pipa, e nse oyun (Abortion) e nfi eniyan rubo, emi eniyan ti Olohun se laala ko to da ko jo yin loju, itajesile po toobe ge ti Olorun wipe ori eje ni a nrin lojojumo.
E nba ni ibuba de omonikeji, e nde awon sile de ara yin nitori owo ati ipo, e yipada ni Oluwa wi oore ofe nbe fun eniyan buburu ti o ronupiwada. Olukuluku njaye ijekuje, e nlo agbara lori alailagbara, e nko ile ise nlanla bi igbati e o ni fi aye sile lo, e tun npon alaini loju, oluponju paapa tun nni oluponju egbe re lara, beni onigbagbo ni won mo o si, e nfi esin boju wu awon iwa buburu gbogbo. Agbere ati pansaga ko ba igbagbo je le nwi lojojumo, beni o je okan ninu ofin ti Olohun fun gbogbo eniyan pe Iwo ko gbodo se pansaga (Eks 20:14)
Olorun so ninu Alkurani pe “E mase sunmo sina (Agbere) dajudaju o je iwa aimo, o si buru ni oju ona ti Olohun (Al-Israi 32) Jesu Oluwa wa pari re pe “Enikeni ti o ba wo Obinrin kan lati se ifekufe sii, o ti ba se pansaga li okan re (Matt 5:28) sugbon loni e ti so orile ede aye di irira nipa pansaga ati agbere, a o wa eyi ti mo nile Olorun yala Soosi tabi Mosalasi, a o wa eyi ti lowo Alufa, Woli, Aafa, Imam.
​
Iwo onigbagbo obinrin ti o fi imura agbere ba opo okunrin laye je loni, nigbati oju Adamu ati Efa la nitori ese won, ti won si ri ipo ti won wa, bi ko se si aso ni akoko na won gbiyanju lati gan ewe opoto po, won fi da ibante fun ara won. Sugbon kini a nri loni ihoho ni opo obinrin nrin kiri larin igboro, o ye ko ni itiju bi ti Adamu ati Efa, e o tile tun fi mo ni ita e o tun wo wa si ibi ti e pe ni ile Oluwa,
​
Iwo akorin emi, opo eniyan ti Oluwa ran o si lati fi orin gbala ni won ntipase orin re di omo ehin Satani, won wa orin ti o le jere okan folorun ninu orin re won o ri ayafi eyiti yoo fi ese kun ese, aye oore ofe la wa le npariwo, iye awon ti o ba ti pase re kose nipa orin re ni Olorun yoo bere lowo re.
Iwo Alufa, Woli, Efajelisiti, Aafa, Imam ati Alhaji, ohun itiju lo je loni pe eyin ti gbogbo eniyan nwo gege bi asiwaju gan ni won tun nba nkan egbin lowo re, bi won o ba pansaga, won o ba oti, be se nsegbe imule le nsegbe alawo, e o tun fi oogun pinle Soosi tabi Mosalasi, oju Olorun nwo yin, o dara ke yipada nitori ojo nbo ti Olorun yoo wipe sebi o gbo ododo ikehin ojo yi. Ko si iwasun ironupiwada mo ayafi ikede ati ipolongo ise iyanu, bi igbesi aye eniti o tile ri iyanu gba tile nbaje nipa iwa buburu, e o bikita.
​
Awa yanu kiri, nje o mo pe ko si ere lori iyanu ti o gba pelu iwa buburu nitori ipari re na inu ina ni, nje o mo pe kosi iyanu to le gba to le tobi to iyanu igbala. Yipada loni ko to pe ju fun o. Arakunrin ati arabinrin, iwo ko gbodo mu oti amupara loro to ntenu re jade nigbagbogbo, beeni lojo isimi (Sunday) iwo pelu Bibeli ni, lojo eti (Friday) iwo pelu Alkurani ati Tesibiu, iwo gbagbe pe oro Olorun so wipe “ki nse fun awon oba lati mu oti waini; beni ki nse fun awon omo alade lati fe oti lile (Iwe Owe 31:4) Alkurani si pari re pe “Eyin onigbagbo ododo dajudaju oti ati tete tita ati orisa bibo ati fifi ofa pin nkan, egbin ni o nbe ninu ise esu, nitorina e jina si ki e le se orire (Qur 5: 90) mase gbagbe pe atelewo ni mo fi njuwe ohun ti won fi bo aye nigbati o pe egberun odun meji lehin iku Oluwa wa (year 2000).