OHUN IJINLE OLORUN APA KEJI
Olorun so nipa isele ti o fa iyapa orile ede alaye ninu Alkurani pe “Awon eniyan ko je nkankan ayafi ijo kansoso sugbon won lodi si ara won.Ti ko ba si titori oro kan ti o gba iwaju lati odo re, a o ba dajo larin won nibi ohun ti won se iyapa re; won sope kilode ti a ko so ami kale fun o lati odo Oluwa re? Nitorinaa wi fun won pe dajudaju ohun ti o pamo ti Olohun ni, nitorinaa e ma reti emi na yoo ma be ninu olureti pelu yin (Qur10:19-20).
KINI ISELE YI? Iwe Genesis lo tan imole si pe gbogbo agbaye ni isokan, lehinnaa awon baba nla wa gbimo po lati mo odi lati wadi Olohun ati lati lodi si ase Olohun eyiti Olorun si da eniyan lede ru, lehinnaa o gegun si aye pe awon eniyan o ni gbede ara won mo, lehinna o tu awon eniyan ka. Olorun wa ran wa nikehin ojo yi pe, lati akoko na ohun kanna loun ran wa si aye sugbon ona ti oun yoo gba ran wa ni yoo fa iyapa ati idaru dapo atipe ki a lo kede Isokan, Alafia, Ironupiwada ati Ijoba Olohun ti a n pe ni Alujona gegebi o se so lati enu Jesu Kristi ati awon Woli re, nitori esin ni awon eniyan fi boju wuwa buburu nikehin ojo yi. Seka 3:10, Qur10:47-49, Isa 19:23-25, Matt16:1-4, Ifihan1 11:1- 8. Ki alaafia ma bisi fun wa, bi a se nka OHUN IJINLE APA KEJI, eyiti nse Awari apa kerin.
IRAN KINNI
Nigbati o pe egberun odun meji (2000 years) ti Jesu Kristi goke re orun ni Oluwa gbe mi lo si enu ona ile nla kan ti mi o si ri opin re, ile nla na si kun fun opo eniyan yala oyinbo tabi eniyan dudu, eniti o ngbe Bibeli tabi eniti o ngbe Alkurani, olukuluku njo won si nyo. Lehinna ni Jesu Kristi wa si enu ona na, ni kete ti o de enu ona na beeni awon eniyan bere si njo sita nikokan, bi won se njo sita be lo nfi owo sami si won ni ori, nigbati o sami ogun eniyan (20 people) lo ba dawo duro, mo ni Olukoni eese ti o fi dawo duro lati ma lo? Ogun eniyan larin opo eniyan woyin, O dahun pe gbogbo olujosin si mi lagbaye niyi yala eniti o nlo soosi tabi mosalasi, oyinbo tabi eniyan dudu. Ogiri ti o si ri lo duro fun soosi (Church) tabi mosalasi (Mosque) sugbon ni odun 2000 yi, ogun eniyan ti o pe ni gbogbo ona won niyi. Ijo ti won si njo, ti won si nyo ni pe nigbati won ba wa ninu ile mimo Olorun ni won nje eniyan Olorun, sugbon ni kete ti won ba jade, iwa won buru ju ti keferi lo. Eyi ni mo gbenu Johannu so ninu iwe ifihan ori kokanla ese ikini pe “A si fi ifefe kan fun mi ti o dabi opa; O si wipe, dide si won Tempili Olorun ati pepe ati awon ti nsin ninu re. (Ifihan 11:1) Olorun gbe odiwon le tempili, pepe ati igbe aye awon olujosin ti njosin ninu tempili ati lori pepe, O si ri ogun eniyan (20 people) ti o pe ni gbogbo ona won ni egberun odun meji yi.
Mo wa bere pe kini yoo gbehin awon eniyan wonyi? O ni eyi ni a fi ran o nikehin ojo yi lati lo wasun ikehin ojo eyiti nse ikede Isokan, Ironupiwada ati Ijoba Olorun fun gbogbo eniyan nitori esin ni awon eniyan fi boju ndese atipe Olorun ki nse Olorun Kristeni tabi ti musulumi bikose Olorun gbogbo agbaye, oun ti mo se si aye ni ko ye eda eniyan, nitorinaa, TANI JESU KRISTI NSE?
IRAN KEJI
Angeli Oluwa mu mi rin irinajo wo inu Orun, mo si nwo ite kan ni oke ti gbogbo ile (ground) re je kiki wura. Ni ori ite yi ni mo ri aga iwasun (pew) kan ti o je kiki wura, niwaju aga iwasun na ni mo ri ilekun kan ti o je ide ati wura sugbon nko ri ogiri tabi yara (room) beeni ite na teju ti nko si ri opin re. Lehinna ni mo ri Jesu Kristi wa siwaju aga iwasun na pelu iwe kekere kan lowo, o si nka gbogbo ohun ti o wa ninu na sugbon nko gbo ohun ti o nka, lehinti o ka tan, o wo inu ilekun na lo, beeni nko ri mo. Lehinna ni mo ri eniyan Olorun kan pelu iwe kan lowo, oun na si wa si ibi aga iwasun yi, oun na ka tire, osi tun wo inu ilekun na lo.
Lehinnaa mo ri ojise Olorun miran, o ka tire, o si tun wo inu ilekun na lo, lehinna ni ojise Olorun miran tun wa, eleyi je apari, oun na ka tire, ki o to kuro nibi aga iwasun na, mo bere lowo Angeli ti o mu mi rin irinajo yi pe, lehin Jesu Kristi Oluwa wa, tani awon meta yi? kini ohun ti won nka ti mi o gbo atipe kini ohun ti won nka wa fun? O dami lohun pe Mose, Elijah ati Elisa ni awon Woli ti iwo ri yi, o wa tesiwaju pe Jesu Kristi Oluwa wa pelu awon woli meta yi ti won le pase ohunkohun ni aye ki o si fidi mule ni orun, ni won jihin ise won fun OGA OGO.
Mo wa bere pe sebi awon woli wonyi sise iranse saaju Jesu Kristi? Angeli na wi fun mi pe, mo gbagbe pe a ti ko pe “ki aye to wa Emi ni ati ki a toda awon oke Emi ni” O wa tesiwaju pe ti Jesu Kristi ati awon woli meta yi ba le jihin ise won fun OGA OGO. So fun awon ojise Olorun ati gbogbo eniyan pe olukuluku ni yoo jihin ise re ni ite idajo. Nitorinaa TANI JESU KRISTI NSE.
TANI JESU KRISTI NSE?
“Atipe ko ni si enikan ninu awon onitira ayafi ki o gba a gbo (Jesu Kristi) ki o to ku, ti o ba di ojo ajinde yoo je eleri tako won” (Qur 4:159). Ti Olorun ba wipe gbogbo eniyan lo nilati gbagbo ki o to ku, ti o ba di ojo ajinde yoo je eleri tako won. Tani Jesu Kristi nse? “Nitori Olorun feran araye toobe ge, ti o fi omo bibi re kansoso fun mi, ki enikeni ti o ba gba a gbo ma ba segbe sugbon ki o le ni iye ainipekun” (Joh 3:16) Olorun feran gbogbo agbaye, ki nse awon to ngbe Bibeli tabi Alkurani nikan nitorina tani Jesu Kristi nse?
Sugbon ni ojo ohun angeli keje, nighati yoo ba fun ipe nigbana ni ohun ijinle Olorun pari, gegebi ihinrere ti o so fun awon iranse re, awon woli (Ifi 10:7) Ati Bibeli ati Alkurani lo fidi re mule eniti Jesu Kristi nse gegebi ohun ti Olorun so ninu ohun ijinle Re fun wa nikehin ojo yi.
1. O JE ORO OLORUN: Ninu Awari akoko Olohun OGA OGO wipe Bibeli ti o nbe ni owo otun ati Alkurani ti o nbe ni owo osi ni Jesu Kristi. Bibeli ati Alkurani fidi re mule pe oro Olorun ni nse. “A si wo ni aso ti a te bo inu eje, a si npe oruko re ni ORO Olorun; o si ni lara aso re ati itan re oruko kan ti a ko: OBA AWON OBA ati OLUWA AWON OLUWA (Ifi 19:13,16) “Ni atetekose ni oro wa, oro si wa pelu Olorun, Olorun si ni oro na…………. Oro na si di ara, oun si nba wa gbe, awa si nwo ogo Re, ogo bi ti omo bibi kansoso lati odo baba wa, o kun fun oore ofe ati otito. (Joh1:1,14). ”Nigbati malaika (Angeli) wipe: Ire mariyama (Maria) dajudaju Olohun fun o ni iro idunnu pelu gbolohun kan (one word) kan lati odo re wa, enikan ti oruko re yoo ma je Masihu Isa omo Mariyama (Messiah omo Maria). Qur 3:45.
2. O JE OMO OLORUN: Ninu Awari kinni, ohun ti o jade lati ori ite OGA OGO wipe, Atipe Jesu na ni Emi OGA OGO fi ropo ara mi si aye pe Olorun ti gbogbo agbaye yoo ri lojukoju ni yi. Bibeli ati Alkurani fidi re mule pe o je omo Olorun.
“Nigbati Oluwa re wi fun awon malaika pe, Emi yoo fi arole kan si ori ile; won wipe ire yoo ha fi si ori ile eniti yoo ma se ibaje lori re, ti yoo si ma ta eje sile; Awa si nse afomo iyin Re, a si nfi ogo fun o, oun Olohun si wipe dajudaju Emi mo ohun ti eyin ko mo” (Qur2:30). eyi je okan ninu iran ti Olorun fi han Annabi.
“Nitori Olorun feran araye toobe ge, to fi omo bibi re kansoso funni, ki enikeni ti o ba gba a gbo ma ba segbe, sugbon ki o le ni iye ainipekun (Joh 3:16)
3. O JE IRANSE OLORUN: Ninu Awari kinni, OGA OGO wipe mo ran si aye lati fi ropo ara mi ni Oba awon Oba ati Oluwa awon Oluwa ti gbogbo agbaye yoo ri ni ojukoju. Ninu iran keji ninu ohun ijinle Olorun yi, Olorun fihan pe Jesu Kristi mu iwe kan ni owo, o si wa siwaju aga iwasun lati jihin ise ti o se laye fun OGA OGO. Bibeli ati Alkurani fidi re mule pe o je Ojise Olorun.
“Ounje mi ni lati se ife eniti o ran mi ati lati pari ise re” (Joh 4:34).
“Emi ko le se ohun kan fun ara mi: bi mo ti ngbo, mo ndajo: ododo si ni idajo mi; nitori emi ko wa ife ti emi tikalara mi bikose ife ti eniti o ran mi (Joh 5:30) “Ati oro won ti won nso pe dajudaju awa ti pa Al-masihu omo Mariyama (Messiah omo Maria) OJISE OLOHUN, bee si ni won ko paa, be si ni won kori kanmo agbelebu sugbon a je ki o ri be loju won ni……….Beko Olorun gbe e lo si odo ara Re, atipe Olohun je eniti o tobi,Ologbon (Qur 4:157-158).
​
4. O JE ONA: Ninu Awari akoko, OGA OGO wipe iwo gbe Bibeli ati Alkurani yi lati lo kede isokan, Alafia, Ironupiwada, ati Ijoba Olorun fun gbogbo eniyan nitori esin ni awon eniyan fi boju. Bibeli ati Alkurani fidi re mule pe ONA ni “Atipe awa fi Annabi Isa (Jesu) omo Mariyama tele ipase won, ti o njeki a mo ododo nipa ohun ti o ti siwaju re ninu At-taorata (ise iranse Mose) A si fun ni Injila (ihinrere) imona nbe ninu re ……….(Qur 5:46)
“Atipe ko si enikan ninu awon onitira ayafi ki o gba a gbo siwaju ki o to ku, ti o ba si di ojo ajinde, yoo je eleri tako won (Qur 4:159) Jesu Kristi papa wa fidi re mule pe “Emi ni Ona, Otito ati Iye: ko si enikeni ti o le wa sodo baba, bikose nipase mi (Joh 14:6).
5. O JE IMOLE: Ninu Awari akoko lehinti OGA OGO pari oro bami so pe iwo gbe Bibeli ati Alkurani yi lati lo kede ihin Isokan, Ironupiwa ati Ijoba Olorun. Mo kigbe pe jeki imole ki o wa, nigbati a da mi pada si aye, gbogbo ibiti o sokunkun ni imole ti tan si.
Ninu iran kinni ninu Awari keta eyiti nse ohun ijinle apa kinni ni Jesu Kristi ti gbe ohun kan le mi lowo ti o dabi igi ti won fi nsare ije (baton) ti o si tun gbe opa fitila le mi lowo pe eyi ni yoo ma tan imole si ohun ti nbe ninu edidi na pe eyi ni ohun ti ara meje na fohun nigbati angeli alagbara na kigbe ti Oluwa wipe e fi edidi di pe ohun ijinle Olohun ni (Ifi 10:7).
Bibeli ati Alkurani fidi re mule pe imole ni. “Atipe awa ti fi Annabi Isa omo Mariyama tele ipase won, ti o jeki a mo ododo nipa ohun ti o ti siwaju re ninu At-taorata. A si fun ni injila (ihinrere) imona ati imole nbe ninu re (Qur 5:46) Jesu Kristi wa fi di re mule pe Emi ni imole aaye, eniti o ba to mi lehin ki yoo rin ninu okunkun sugbon yoo ni imole iye (Joh 8:12). Ona yowu ti o ba wa gba a gbo nje o nse ife baba re ti o je ORO Olorun gegebi Oluwa se so ninu iwe mimo pe “Ki nse gbogbo eniti npe mi Oluwa, Oluwa ni yoo wo ijoba orun; bikose eniti nse ife Baba mi ti nbe ni orun (Matt 7:21).