top of page

 E JE MIMO

 

Oluwa wipe mo so fun Israeli lati ya ara won si mimo fun ojo meta, ki won si tun fo aso won  mo, ki won mase sunmo ara won, ki won si mura lati pade Emi Olorun ni ojo keta nitori Emi yoo sokale si ori oke Sinai. Sugbon ni ojo keta ti Emi Olorun sokale, awon omo isreali ko le duro niwaju MI pelu bi won se ya ara won si mimo to. Oluwa wa bere lowo mi pe: Nje iwo mo pe egberun meedogun meeli (15,000 miles) ni ibiti mo wa si ibiti awon omo isreali wa, sibe won o le duro niwaju MI. Awon eniyan yoo ma gbe ninu ese sibe won o ma ro pe mo wa larin won, won o si tun ma kepe Emi Olorun fun ise iyanu. E je mimo nitori Emi Olorun je mimo atipe alaimo kan ko le wo ijoba mi nitori ijoba orun ki nse ile elese ti ko ronupiwada.

 

Iwe mimo Bibeli ati Alkurani si fidi ohun ti Olorun so yi mule pe “E je mimo nitori Emi Olorun je mimo” (1Pet 1: 16). Alkurani wa pari re pe “Dajudaju eniti o ba je mimo ti jere” (Qur 87:14) ko si ibiti yoo jere bikose ijoba Olorun.

 

                                                        OLODODO YOO FO

 

Oluwa mu mi lo ninu emi rin irinajo lo si ara odi nla kan, eyiti won fi ide ati wura se, ti o si ndan, ori eyiti o kan orun, lekanna ni awon eniyan bi agbaye nsare lo si ara odi na lati gun lo si orun, bi won se ngbiyanju lati gun beeni owo (hand) ati ese (leg) awon eniyan nyo si isale, won o si le gun, lehin opolopo wahala won. Mo wa bere pe kini itumo eyi? Oluwa dahun lati inu orun wa pe bi yoo ti ri nikehin ojo niyi nitori kiki awon olododo nikan lo le fo.

E yipada kuro ninu aisododo gbogbo nitori didasi ti Oluwa da o si doni ni pe ki o le wo igbe aye aisododo ana, ki o si satunse loni nitori o mo, ohun ti o le sele lola. Iwo a fesin boju luwe ninu aisododo gbogbo, yipada loni nitori olododo nikan lo le fo nikehin.

                                        

                                        

  BI ENIKENI O RI O, OLOHUN RI O.

Olorun wipe emi ki nse Olorun kristeni tabi ti musulumi bikose Olorun gbogbo agbaye pe ohun ti mo se si aye ni ko ye eniyan sugbon awon eda eniyan nikehin ojo yi wa fi esin boju nigati iwa ati ise won buru ju ti keferi lo.

Adam ati Efa sa si arin igi ogba lati fi ara won pamo fun Olorun, nitori won gbagbe pe bi eniyan o ri won, Olorun nri won. Oju Olorun nlo soke sodo ni origun merin agbaye. I1kro 16:9. Nitori Dafidi wipe ko si bi to le fi ara pamo si fun Olohun. O.D 139:2 - 12

 

Kini awon ohun ti onigbagbo nlo nikehin ojo yi lati fi ara won pamo fun eniyan ati Olorun?

 

1. ESIN: Kristeni ni mi, Musulumi ni mi, abe re ni opolopo nsapamo si lati fi bo iwa buburu won mole nigbati won o bikita nipa ati se ife Olorun. Musulumi tabi kristeni ni mi ni opolopo fi ntan eniyan je loni beeni e o le tan Olorun je. Nitori beniyan o ri o, Olorun nri o. Igbe aye awon omo ehin Jesu ni awon ara Antioku ri ti won fi pe won ni kristeni (Ise 11:26) pe won fiwa jo Kristi. Ibrahimo (Abrahamu) lo be fun eniti yoo ma saaju won ninu isin lehinti o gbe pepe ro fun Olorun, ti Olorun si dahun wipe se ko le juwojuse (musulumi) fun oun Olorun oba. Ati onigbagbo ti ko fiwa jo Kristi ateyi ti ko juwojuse fun Olorun lo npe ara re ni kristeni tabi musulumi. Beniyan o ri o Olorun nri o.

 

2. BIBELI ATI ALKURANI: A nlo Bibeli tabi Alkurani loni lati bo iwa buru mole tabi fi iru enito je pamo. Bi enikeni ba ri o pe onigbagbo to ngbe Bibeli tabi Alkurani ni o, yoo ro pe okan ninu onigbagbo ni o, beeni iwa re buru ju ti alaigbagbo lo, o si se ba gbe tabi ba dowo po. Opo igba ni onigbagbo loni nlo ese oro Olorun lati fi gbe iwa buburu won lese nipa fifun ni itumo ti won. Beniyan o ri o, Olorun nri o.

 

3. LILO SI ILE OLUWA ATI ADURA: Yala soosi tabi Mosalasi, opo onigbagbo nfi lilo si ile Olorun nigbagbogbo fi ara won pamo nigbati lilo sile Olorun ko farahan ninu aye won. Nigbati o ba kan oro owo ati ifekufe miran yoo so igbagbo sonu. Beniyan o ri o, Olorun nri o. Opo fi ara won pamo sabe wakati marun, gbigbe age wakati marun lati kirun pelu iwa buburu, eniyan lo le fi eyi tan je, o le tan Olorun ti yoo san fun olukuluku gegebi ise re je tabi iwo ti o pe rare ni kristeni to ngbawe pelu adura wakati marun, adura agogo mefa owuro, agogo mesan owuro, mejila osan, meta ati mefa irole pelu iwa buburu, Beniyan o mo iru enito je Olorun nri o.

 

4. ORUKO JESU KRISTI: Opo sapamo si abe oruko Jesu pe mo gba Jesu Kristi gbo sibe oruko na ko gba iwa janduku, ati iwa buburu miran kuro lowo re, bi eniyan o ri o Olorun nri o atipe ojo kan nbo ti yoo wipe Emi o mo o ri (Matt 7:21-23).

 

5. ORUKO OBA ALLAH ATI ANNABI MUHAMMADU: E sapamo si abe oruko oba Allah ati ojise re loni, awon eniyan si nwo o pe onigbagbo ododo ni o, laimo pe iwa re buru ju teni ti ko gbagbo lo. Bi o ba ro pe o le tan eniyan je, o le tan Olorun je. Bi Annabi Muhamo o ba se ife Olorun, Olohun o le pe ore re (Qur 7:196).

 

6. IMURA BI KRISTENI TABI MUSULUMI: Onigbagbo nlo imura aso lati fi igbe aye won pamo fun eniyan gegebi onigbagbo beeni o le fi ara pamo fun Olohun, Oro Olohunso ninu Alkurani pe “ki aso re je mimo, ki o si jina si aimo” (Qur 74:4-5) eyiti nse igbe aye iwa mimo, onigbagbo loni ko yato si awon ti Jesu so nipa re wipe “Beeni eyin nfarahan ni ode biolododo fun eniyan, sugbon ninu, e kun fun agabagebe ati ese (Msatt 23:28). Beniyan o ri o, Olorun nri o.

Ki alaafia Olohun ki o ma biisi fun gbogbo eniyan bi a se nka Awari kerin, eyiti nse OHUN IJINLE OLORUN APA KEJI.

bottom of page